Home ÀKỌ̀TUN Àwọn aṣòfin Ọ̀yọ́ fí aṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn, ìfúnpá àti gbérí ọdẹ buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 4, 2020

Àwọn aṣòfin Ọ̀yọ́ fí aṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn, ìfúnpá àti gbérí ọdẹ buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn.

Àwọn aṣòfin Ọ̀yọ́ fí aṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn, ìfúnpá àti gbérí ọdẹ buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí òrọ̀ bá ń pẹ́ nílẹ̀, ó máa ń gbọ́n ni àti pé bí iṣẹ́ kò bá pẹ́ni, ẹnìkan kìí pẹ́’sẹ́, ni àwọn ilé Aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ àti Ogun fí bíbuwọ́lu àbádòfin ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ṣe.

Lọ́jọ́ ìṣègùn yìí ní àwọn méjéèjì jókòó jíròrò lórí àbádòfin náà, tí wọ́n sì buwọ́lu òfin tó gbe ìdàsílẹ̀ ikọ̀ aláàbò náà sílẹ̀ nípìńlẹ̀ wọn
Ṣaájú àsìkò yìí ni àwọn Ìjọba ilẹ̀ kaarọ o jíire àti Ìjọba àpapọ̀ ti fẹnu kò sí pé, kí àwọn ìpínlẹ̀
kọ̀ọ̀kan padà lọ fi òfin gbe ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ wọn.

Yàtọ̀ sí ìpínlẹ̀ Èkó tí ó mú àtúnṣe bá òfin tó ṣe ìdàsílẹ̀ ikọ̀ aláàbò Neighbourhood Watch, tí ó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn ìpínlẹ̀ tó kù ṣẹṣẹ bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fi òfin gbe ìdàsílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn lágbègbè wọn ni.

Ní tí àwọn Aṣòfin Ọyọ,asọ Àmọ̀tẹ́kùn ni wọ́n kósí wá sí Ilé.
Ń ṣe ni àwọn aṣòfin Ilé aṣòfin Ọ̀yọ́ kó àǹkóò aṣọ tó jọ àwọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn yẹbẹyẹbẹ, wá sí Ilé láti fi ìfarajìn wọn hàn lórí i sísọ àbádòfin yìí di òfin sàn án.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …