Home ÀKỌ̀TUN Okùnrin ọmọ Italy kan ti kó àrùn Coronavirus wọ Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ètò ìlera
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 28, 2020

Okùnrin ọmọ Italy kan ti kó àrùn Coronavirus wọ Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ètò ìlera

Okùnrin ọmọ Italy kan ti kó àrùn Coronavirus wọ Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ètò ìlera

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rí sí ìsàkóso àrùn ti sọ pé àrùn Coronavirus tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ COVID-19 ti tàn dé Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tó fi léde lójú òpó Twitter rẹ̀, ó ní “Mínísítà fún ètò ìlera ti fi Ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àrùn Coronaviorus ti ṣẹ́yọ nílùú Eko.”

Àtẹ̀jáde ọ̀hún tẹ̀síwájú pé, wọ́n fìdí àrùn ọ̀hún múlẹ̀ lọ́jọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n Oṣù Kejì ọdún 2020, léyìí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Nàìjíríà láti ìgbà tí àrùn náà ti ṣẹ́yọ lósù Kínní ọdún lórílẹ̀-èdè-ede China.

Ẹni tó ní àrùn náà jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Italy tó ń ṣe iṣẹ́ ajé ní Nàìjíríà.

Ọkùnrin náà rìnrìn àjò wá sí ìlú Eko láti ìlú Milan lọ́jọ́ karùndínlọ́gbọ̀n Oṣù Kejì, kí wọ́n tó sàyẹ̀wò rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́sẹ́ ìṣègùn wà ní Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó.

Èyí ni ìgbákejì tí àwọn elétò ìlera yóó fìdí àrùn náà múlẹ̀ nílẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣaájú fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Algeria àti ìhà Àríwá Áfírìkà.
Ní báyìí, àjàkálẹ̀ àrùn Coronavirus ọ̀hún ti tàn dé orílẹ̀-èdè tí kò dín ní ogún káàkiri àgbáyé lágbègbè Asia, Yúróòpù, àti Áfírìkà.

Ṣaájú ni Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti kọkọ ṣọ pé kò sí àrùn coronavirus ní ìpínlẹ̀ náà, lẹ́yìn tí àyẹ̀wò fihàn pé ọmọ orílẹ̀-èdè China kan kò ní àrùn COVID-19 ọ̀hún.

Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà fún ètò ìlera Nàìjíríà, Osagie Ehanire ti sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ìjọba àpapọ̀ ń ṣe iṣẹ́ takuntakun láti ri pé àrùn náà kò tàn kálẹ̀ ju bóṣe lọ ní Nàìjíríà.

Osagie ní iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí gbogbo àwọn tí ọkùnrin ọ̀hún bá pàdé nínú ìrìnàjò rẹ̀ láti ilẹ̀ Italy sí ìlú Èkó.

Ó wá rọ àwọn ará ìlú láti má lo ojú òpó ìkànsíraẹni lórí itàkùn àgbáyé láti máa pín àwọn Ìròyìn òfegè nípa àrùn náà, léyìí tó leè fa ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn èèyan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…