Home ÀKỌ̀TUN Òǹtajà dákú níbi ìjàm̀bá iná ni Balogun ti ìlù Eko
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 29, 2020

Òǹtajà dákú níbi ìjàm̀bá iná ni Balogun ti ìlù Eko

Òǹtajà dákú níbi ìjàm̀bá iná ni Balogun ti ìlù Eko
Láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

“Egberin ote, bi a ti n pa okan ni okan n ru”. Afi ki Eledua ba wa dawo aburu duro ti o ba se pe ese lo po.
Ko ti pe ose kan ti bilionu naira oja jona ni oja Amu to wa ni Eko, abala kan ni oja gbajugbaja Balogun ni o tun gbina ni osan oni nibi ti arakunrin kan ti ni ki oun ro epo si inu jenereto re ti o n sise lowo, ti epo re fere tan.
Ibi ti o ti n se eyi ni ina ti bu gbamu ti owo awon to wa ni agbegbe naa ko si laa ina mo.
Ki a to wo ki a to fo,ina ti bere si ni be wo awon soobu naa ni okookan. O nira fun opo oluranlowo lati ri ina naa pa nitori pe ori oke ni ina naa ti bere.
Koda,igba ti awon panapana gan-an de, ko rorun fun won lati ri ibi duro si nitori kikun ti oja naa maa n kun. Eyi gba awon panapana ni ogbon iseju ki won to ri ibi gbe oko si maa sise.
Won pa ina naa,Olorun ko si je ki emi kankan ba ina naa lo ayafi obinrin kan ti o daku nigba ti o ranti iye dukia to ba ina naa lo. Pelu iranlowo awon eniyan, obinrin naa ji saye.
Awon eniyan gbiyanju die loja naa paapaa ni awon ibi ti ina naa ko tete de, won bere si ni ju awon oja si isale lai bikita jiji.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…