Home ÀKỌ̀TUN Bí ìjọba bá kọ̀ láti san owó o wa, a ó da iṣẹ́ sílẹ̀ – ASUU
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 29, 2020

Bí ìjọba bá kọ̀ láti san owó o wa, a ó da iṣẹ́ sílẹ̀ – ASUU

Bí ìjọba bá kọ̀ láti san owó o wa, a ó da iṣẹ́ sílẹ̀…ASUU

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ASUU, ti pàṣẹ fún àwọn olùkọ́ Fásitì láti da iṣẹ́ sílẹ̀ ní ìgbà kúùgbà tí Ìjọba bá tí kọ̀, láti san owo oṣu wọn.

Alága ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Abeokuta, Adebayo loti sọ fún akọ̀ròyìn pé àwọn ti fi àṣẹ náà ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà.

Adebayo ní abajade ìpàdé ẹgbẹ́ ni wí pé tí Ìjọba bá kọ̀ láti san owó oṣù àwọn kan, gbogbo àwọn ni àwọn yóó da iṣẹ́ sílẹ̀.

Bákan náà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba pé wọ́n lọ gba ẹ̀yìn ba ẹbọ jẹ́ lórí ètò ìsanwó òṣìṣẹ́ ètò IPPIS.

Ètò IPPIS ni Ìjọba pèsè láti má a san owó oṣù òṣìṣẹ́ láti inú àpò ìṣúná kan náà fún owó gbogbo oṣù òṣìṣẹ́ Ìjọba, eléyìí tí Asuu ní ètò ìsanwó yìí yóó gba àṣẹ tó gbé àwọn dúró láti le dádúró láì sí àfikún ìjọba lórí ètò ìṣúná àwọn.
Àmọ́ Ìjọba ní Ìdí tí àwọn fi gbé e kalẹ̀ ni láti gbé ogun ti ìwà ìbàjẹ́ àti jẹgúdújẹrá tó wà ní ẹ̀ka òṣìṣẹ́ Ìjọba lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpàdé àti akitiyan láti ọ̀dọ̀ ọ ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU, wọ́n gbà pé kí wọ́n gbé àjọ UTAS sílẹ̀ tí yóó gbogun ti ìwà ìbàjẹ́ ni ètò ìṣúná ilé ẹ̀kọ́ gíga, eléyìí tí kò nílò ètò IPPIS.

Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU fi ẹ̀sùn kan Ìjọba pé wọn kò dúró lórí ọ̀rọ̀ wí pé kí wọ́n gbé àjọ UTAS yẹ̀wò, àmọ́ tí Ìjọba pàṣẹ pé òṣìṣẹ́ tí kò bá sí lórí ètò ìṣúná IPPIS kò ní gba owó Oṣù Kínní, ti ọdún 2020 tí ó ń parí ní ọ̀sẹ̀ yìí.

Láìpẹ́ yìí ni Ààrẹ Buhari pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ lásìkò tí òun ṣe ìpàdé pẹ̀lú wọn láti rí pé wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Adamu Adamu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…