Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ọlọ́pàá ẹnu ọ̀nà káńṣù náà ṣetán láti wọ́n eṣinṣin tó bá ta fírí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 28, 2020

Àwọn ọlọ́pàá ẹnu ọ̀nà káńṣù náà ṣetán láti wọ́n eṣinṣin tó bá ta fírí

Àwọn ọlọ́pàá ẹnu ọ̀nà káńṣù náà ṣetán láti wọ́n eṣinṣin tó bá ta fírí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olú iléeṣẹ́ Ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ìbàdàn, Ibadan North, tó kalẹ̀ sí agbègbè Agodi-Gate n’Ibadan, náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ tí àwọn òṣìṣẹ́ kò ti ní àǹfààní láti wá sí ẹnu iṣẹ́ lónìí.

Gboin-gboin ni ẹnu ìloro Ìjọba ìbílẹ̀ náà wà ní títí pa lásìkò tí ìròyìn Òwúrọ̀ se àbẹ̀wò síbẹ̀.

Wámú -wámú ni àwọn agbófinró dúró síbẹ̀, tí esinsin bá si ta fírí níbẹ̀, wọn yóó wọn ni.

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà, tó ní kí akọ̀ròyìn fi orúkọ bo òun lásìírí ṣàlàyé pé, láti òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn alákòóso Ìjọba ìbílẹ̀ náà ti ránṣẹ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ wọn.

Àwọn ló ṣọ pé kí kóówá òṣìṣẹ́ jòkó sílé lónìí títí di ọjọ́ mìíràn, ọjọ́ re, nípaṣẹ̀ ìròyìn tó ń jà ràn-ìn ràn-ìn pé àwọn Alága ìbílẹ̀ àná nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti ń gbèrò láti padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn lónìí.

Ṣaájú ni agbẹjọ́rò àgbà lórílẹ̀-èdè yìí, Abubakar Malami ti ránṣẹ́ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé láti dá àwọn Álága ìbílẹ̀ tẹ́lẹ̀rí náà padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn, tí Gómìnà sì fèsì pé agbẹjọ́rò àgbà orílẹ̀ yìí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fí ọwọ́ lalẹ̀ nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…