Home ÀKỌ̀TUN Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n ti sin oku aṣàájú olóṣèlú náà lọ́sàn-án Ọjọ́bọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 24, 2020

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n ti sin oku aṣàájú olóṣèlú náà lọ́sàn-án Ọjọ́bọ

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n ti sin oku aṣàájú olóṣèlú náà lọ́sàn-án Ọjọ́bọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ba akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ipapòdà aṣojú pàtàkì kan nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC ìpínlẹ̀ Ọyọ, Alhaji Babatunde Oreitan.

Oreitan ni wọ́n dédé bá òkú rẹ̀ nínú àgbàrá ẹjẹ lọsan Ọjọ́rú, nínú ilé rẹ̀ tó ń bẹ ní agbègbè Ọ̀rẹ́ méjì nílùú Ìbàdàn.

Lòdì sí Ìròyìn tó ń jà ràn-ìn ràn-ìn pé àwọn agbébọn kan ló ṣekúpa á Oreitan lásìkò tó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé rẹ̀, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàlàyé fún pé, ìbọn kọ́ ní wọ́n fi gbẹ́mìí olóògbé náà.

Ó ní abẹ tí ó mú ni wọ́n fi gé iṣan ọrùn ọwọ́ àti iṣan ẹ̀sẹ̀ olóògbé náà, èyí tó mú kó pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹjẹ, kíkú tó pajú ẹ̀ dé . À mọ́ iṣẹ́ ìwádìí ń tẹ̀síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú tó jákùn ẹ̀mí èèkàn olóṣèlú ọ̀hún patí .

Bákan náà ni ọ̀kan lára àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ olóògbé, Mikail Adeleye sọ fún akọ̀ròyìn pé, òun àti ẹnìkan ni àwọn jọ wá olóògbé wá sí Ilé rẹ̀ lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Ibi tí wọ́n sì ti ń wá Alhaji Oreitan kiri inú Ilé ni wọ́n ti dédé kàn án nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti bo àṣírí òkú olóògbé ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán Ọjọ́bọ, iléeṣẹ́ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Ọyọ ti jẹ́jẹ́ láti ṣe awari àwọn ìkà ènìyàn tó ṣiṣẹ́ láabi ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…