Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́ ní àwọn afurasí mẹ́rin kò mọwọ́-mẹsẹ̀ lórí ikú Sugar
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 24, 2020

Ilé ẹjọ́ ní àwọn afurasí mẹ́rin kò mọwọ́-mẹsẹ̀ lórí ikú Sugar

Ilé ẹjọ́ ní àwọn afurasí mẹ́rin kò mọwọ́-mẹsẹ̀ lórí ikú Sugar

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ gíga tó wà nílùú Ìbàdàn ti dá àwọn afurasí mẹ́rin sílẹ̀, àwọn tí wọ́n ń jẹ́jọ́ lórí ikú tó pa aṣojú-ṣòfin tó ń sojú ẹkùn ìdìbò Lagelu Akinyẹle nípìńlẹ̀ Ọyọ, Aṣòfin Temitọpẹ Olatoye, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Sugar,

Àwọn afurasí náà ni Akinmoyede Olafioye, tó jẹ́ akójàánu ilé tẹ́lẹ̀ nílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Rafiu Adebayọ, tó fi mọ́ Rasheed Ọladele ati Kazeem Ayinde.

Adájọ́ Adegbọla Mufutau, lásìkò tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ kéde pé àwọn olùjẹ́jọ́ náà kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn nítorí ikọ̀ olùpẹ̀jọ́ kùnà láti fìdí ẹ̀rí tó dájú múlẹ̀ pé àwọn olùjẹ́jọ́ ọ̀hún jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Aṣòfin Temitope Olatoye Sugar làwọn èèyàn kan ṣekúpa lọ́jọ́ Sátidé, ọjọ́ Kẹsàn oṣù kẹta ọdún 2019 lásìkò ìdìbò gómìnà àti tilé aṣòfin ìpínlẹ̀ tó wáyé yíiká orílẹ̀èdè wa Nàìjíríà.

Nígbà tó ń fèsì lórí ìdájọ́ náà, Asofin Akinmoyede ni Ọlọ́run ti dá òun láre lórí àwọn ẹ̀sùn ìpànìyàn tí wọ́n fi kan òun lórí ikú Sugar, tí òtítọ́ sì ti fojú hàn pẹ̀lú ìdájọ́ náà pé òun kò lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.
Olafioye wá lo àkókò náà láti kẹ́dùn púpọ̀ pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé ọ̀hún, pẹ̀lú àdúrà pé Ọlọ́run yóó tù wọ́n nínú láti gba àdánù náà mọ́ra.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…