Home ÀKỌ̀TUN Ha! Àbí ìbọn ni wọ́n fi gbẹ́mì Alhaji Fatai Yusuf ? “ọkọ olóyún”
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 24, 2020

Ha! Àbí ìbọn ni wọ́n fi gbẹ́mì Alhaji Fatai Yusuf ? “ọkọ olóyún”

Ha! À bí ìbọn ni wọ́n fi gbẹ́mì Alhaji Fatai Yusuf ? “ọkọ olóyún”

Fẹ́mi Akínṣọlá

À fi kí Ọlọ́run ṣá má a di okùn ẹ̀mí wa mú nírìnàjò wa gbogbo nínú ewu òkuǹkùn biribiri ayé yìí. Ó tí di ìròyìn ajániláyà pàtì pé
Alhaji Fatai Yusuf, tí ọ̀pọ̀ mọ sí ọkọ olóyún là gbọ́ pé àwọn òsìkà ẹ̀dá kan tí yìnbọn pa lásìkò tó ń rìnrìn àjò láti Isẹyin sí Abeokuta.

Ìròyìn ṣọ pé ,ní kété tí isẹlẹ naa sẹ ní wọn ti gbé e lọ sílé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Ìròyìn mii tí o sunmọ òótọ́ ni pé , ògbóǹtarìgì ìlúmọ̀ọ́ká oníṣègùn ìbílẹ̀ tí se ọmọ bibi ìlú Òtu náà kò rù ú là lọ́wọ́ ikú.

Nígbà tí ó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀,alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Gbenga Fadeyi fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé bí ọwọ́ aago mẹ́rin ààbọ̀ nírọ̀lẹ́ ní àwọn òsìkà ẹ̀dá náà tẹ́nikẹ́ni ò tíì mọ̀ ṣiṣẹ́ ibi náà.

Fadeyi, tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, Kọmíṣọ́nnà ọlọpàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ọ̀gbẹ́ni Shina Olukolu tí kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú àwọn ìgbákejì ọ̀ga ọlọpàá mìíràn láti lọ sàyẹ̀wò ojúkòró ìsẹ̀lẹ̀ náà.
Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàfikún ẹ̀ pé, lọ́gán náà ni Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ti gbé ìgbìmọ̀ asòfinntótó alágbára kan dídè fún ìsàwárí ati àmúdópin ìjìyà fún àwọn tí aje ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́soríkọ́ náà bá sí mọ́ lórí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…