Home ÀKỌ̀TUN A ó ri dájú pé Diezani padà wálé láti jẹ́jọ́ ìwa àjẹbánu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 23, 2020

A ó ri dájú pé Diezani padà wálé láti jẹ́jọ́ ìwa àjẹbánu

A ó ri dájú pé Diezani padà wálé láti jẹ́jọ́ ìwa àjẹbánu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC ti ní àwọn yóó ri dájú pé Mínísítà fún epo rọ̀bì, Diezani Allison-Madueke tó ń jẹ́jọ́ ìwà jẹgúdújẹrá yóó padà wálé, kí ọdún tó parí láti wá wí tẹnu rẹ̀.

Alága Àjọ EFCC, Ibrahim Magu ló fi èyí léde lásìkò tó ṣe Àbẹ̀wò sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní ìlú Ìbàdàn.

Magu fi ẹ̀sùn kan àwọn alábàáṣisẹ́pọ̀ wọn nílẹ̀ òkèèrè pé, wọ́n ń dáàbò bo Diezani ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì láti dènà àti wá jẹ́jọ́ rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àmọ́ ó fikún -un pé, àjọ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ọ̀nà mìíràn láti fi ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè láti ri wí pé Mínísítà fún epo bẹntírò tẹlẹri náà, padà wá sílé láti wá jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́.

Alága àjọ EFCC ní, inú òun bàjẹ́ gidi gidi pẹ̀lú bó ṣe nira, tó sì ṣòro láti jẹ́ kí àwọn tó ń hu ìwà ìbàjẹ́ fi ojú winá òfin, kí àwọn ẹlòmíràn le kọ́gbọ́n nípa rẹ̀.

Magu ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣa ipá wọn láti fi ojú àwọn ọ̀bàyéjẹ́ hàn.Ó ní kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ ìṣesí náà, kí àwùjọ leè dára sí i.

Nípa ètò ìdìbò gbogboògbò tó kọjá, Ọ̀gá Àjọ EFCC náà fikún un pé, àwọn ó ri dájú pé àwọn gbógun ti ìwà rírà ìbò àti títa ìbò lórílẹ̀-èdè Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …