Home ÀKỌ̀TUN Asiwaju sí aso̩ lójú eégún “operation Àmò̩té̩kùn”
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 22, 2020

Asiwaju sí aso̩ lójú eégún “operation Àmò̩té̩kùn”

“Asiwaju sí aso̩ lójú eégún “operation Àmò̩té̩kùn”
Láti o̩wò̩ Yínká Àlàbí
Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu to je asiwaju agba ninu egbe oselu APC ni gbogbo aye ti n wa kiri lati ojo ti Abubakar Malami ti ni idasile Amotekun ko ba ofin mu.
Abubakar Malami ni olori eto idajo ni orileede yii. Gbogbo awon eniyan lo fe mo ibi ti Tinubu fi si lori oro Amotekun.
Awon kan ni Tinubu naa lo daa sile fun odun 2023. Awon kan ni Tinubu ko tile fara mo idasile re rara, won ni gbogbo nnkan ti owo Tinubu ba wa, ko si baba eni to le so pe ko ba ofin mu ni orileede yii.
Boya die lara awon awuyewuye yii naa lo ta si Asiwaju leti to fi da si oro naa.” Yoruba bo, won ki ” eti oba nile,eti oba loko,eniyan lo n je bee”.
Tinubu ni ko si ohun to lodi si idasile ajo idaabobo Amotekun. O ni eyi ko si salaye pe agbara ijoba apapo ko ka aabo ilu mo. O ni iranlowo ni Amotekun maa je fun awon ologun nitori pe ” alejo loju lasan ni,ko le rina to onile”.
Asiwaju gba awon gomina mefeefa niyanju lati lo se ipade pelu Malami, ki won je ki o mo idi idasile ajo naa. Ki won si se pelu Aare Mohammadu Buhari naa bo se ti wa nile.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…