Home ÀKỌ̀TUN Ilé-ẹjọ́ tó ga jù ní Samuel Ortom náà ló tún jáwé olúborí ní Benue
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 21, 2020

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù ní Samuel Ortom náà ló tún jáwé olúborí ní Benue

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù ní Samuel Ortom náà ló tún jáwé olúborí ní Benue
Láti ọwọ Yínká Àlàbí
Iroyin yajoyajo to wole bayii lo n jeri sii bi ile ejo to ga ju lo to fi ikale si ilu Abuja se da ejo oludije fun ipo gomina ni ipinle Benue, iyen Emmanuel Jime ti egbe oselu APC nu bi omi isanwo.
Awon adajo meje ti Adajo Olabode Rhodes-vivour je olori fun ni won se idajo naa ni nnkan bii ogbon iseju seyin.
Ile ejo ni gbogbo awijare egbe oselu APC ko lese nile, nipa idi eyi ki gomina Ortom ti egbe oselu PDP si maa se ijoba re lo ni alaafia.
Ti a ko ba gbagbe, ana ode yii naa ni ile ejo yii da ejo awon gomina merin nigba ti ti ipinle Imo waye ni ose to koja bi o tile je pe iwode si n lo kaakiri nipa idajo naa.
Awon ti ko te lorun n se iwode bee si ni awon ti ejo naa gbe n se idunnu kiri ilu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…