Home ÀKỌ̀TUN Ìjàm̀ba iná gbẹ̀mí èèyàn méjì l’Ékòó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 20, 2020

Ìjàm̀ba iná gbẹ̀mí èèyàn méjì l’Ékòó

Àrìnfẹsẹ̀sí ò kan máìlì, bẹ́ẹ̀ ìjàǹbá ò nílé kan pàtó àfi kí Ọlọ́run ṣá máa kó àwa àti ẹbí i wa yọ .Ewu ńlá míì tún tí yọjú gúlẹ́ bí ó se di pé ọ̀pá epo bẹntírò kan tún ti bú gbàmù tí iná sì sọ lágbègbè Òkè odò ní ìlú Èkó.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn tó ń jáde láti agbègbè náà ṣe sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá bii tirela , oko ayokele ati awon ile gbigbe pelu ohun ini won lo ba ina lo.

Ìwádìí fihàn báyìí pé opa epo yii ti bere si ni yo jo lati irole ana ti awon eniyan agbegbge naa ko tete pe akiyesi awon agbofinro sii. Eyi lo mu ki ina na bureke lale titi di oru. Nnkan bii aago meji oru ni awon panapana to segun ina naa.
Emi eniyan meji tabi meta lo ba isele buruku naa lo. Awon agbofinro gba awon eniyan niyanju lati maa tete pe akiyesi ijoba tabi Baale tabi olori agbegbe si iru nnkan bee nitori ojo miiran.

Kí Ẹlẹ́dàá má jẹ́ á rìn níjọ́ ebi ń pọ̀nà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …