Home ÀKỌ̀TUN Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá….Wasiu Ayinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 17, 2020

Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá….Wasiu Ayinde

Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá….Wasiu Ayinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúgbajà olórin fújì, Wasiu Ayinde tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ oyè máyégún Ilẹ̀ Yorùbá ti sọ fún akọ̀ròyìn pé, oyè náà kìí ṣe láti bùgá, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti tún ilẹ̀ Yorùbá ṣe.

Olúomo ṣàlàyé pé Iṣẹ́ òun àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi Máyégún ni láti rí pé àlàáfíà jọba nílẹ̀ Yorùbá.

“Láti kékeré ni mo ti ń sapá láti rí i pé Nàìjíríà tẹ̀síwájú, bẹ̀rẹ̀ láti àdúgbò tí mò ń gbé títí dé ilẹ̀ òkèèrè. Ìdí nìyẹn tí mo ṣe ń bá àwọn olóṣèlú ṣepọ̀ . Mò ń báwọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.”

Lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn” tó ti di ariwo lẹ́yìn tí Ìjọba àpapọ̀ ní kò bá òfin mu, ó sọ pé kò sẹ́ni tó mọ ọmọ pọ̀n bí ọlọ́mọ, fún Ìdí náà, kò sí èèwọ̀ nínú ká ṣọ́ra ẹni, ṣùgbọ́n kí Ìjọba fi ojú ṣùnùkùn wo ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…