Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Buhari àti ọ̀gá ọlọ́pàá mọ̀ nípa “opration Àmọ̀tẹ́kùn” – Fayemi
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 16, 2020

Ààrẹ Buhari àti ọ̀gá ọlọ́pàá mọ̀ nípa “opration Àmọ̀tẹ́kùn” – Fayemi

Awuyewuye to n lo lowo lori eto aabo ile Yoruba ti awon gomina mefeefa fowo si ni alaga awon gomina fesi si bayii.
Alagba kayode Fayemi to je gomina ipinle Ekiti ati alaga awon gomina ni Naijiria ni “a kii soola lodo ki labelabe ma mo”. O ni oun ko mo ohun ti Abubakar Malami ni lokan to fi ni ijoba apapo ko fowo sii nitori pe Aare Muhammodu Buhari ati oga olopaa patapata IG Adamu mo nipa idasile awon ajo.
Fayemi ni o ye ki ijoba apapo maa gbe osuba rabande fun awon ti awon da ajo naa sile ni nitori pe eto aabo to je eru ijoba apapo ni awon n ba ijoba apapo gbe yi.
Gomina Fayemi ni ko si isoro rara, awon gomina maa se ipade, awon si maa mo igbese ti o kan nipa “operation Amotekun”.
Fayemi ni gege bi awon kan se n gbee poori enu nipa ero lati lo won fun oselu, o ni ko si ohun to joo rara, awon ko da won sile lati fi se oselu. O ni gbogbo awon ti awon da won sile gan-an ko si ninu egbe kan naa.
O ni idi pataki ti awon fi da ajo naa sile ko ju ti eto aabo to fe mehe lo, o ni opo igba ni awon olopaa maa n so pe awon ko le wo awon igbo kijikiji lati lo maa le awon ajinigbe kiri sugbon awon “Amotekun’ le maa gbe inu igbo nitori pe awon ajinigbe naa maa n gbe inu igbo, awon ti won ba ji gbe naa, inu igbo naa ni won maa n gbe won lo. Eyi lo bi ajo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…