Home ÀKỌ̀TUN Págà! Ẹja ńlá lọ lómi .Bàtá jákùn ó dìkàlẹ̀ , àgbà òṣèré Arígbábuwó parí eré sálákeji.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 15, 2020

Págà! Ẹja ńlá lọ lómi .Bàtá jákùn ó dìkàlẹ̀ , àgbà òṣèré Arígbábuwó parí eré sálákeji.

Págà! Ẹja ńlá lọ lómi .Bàtá jákùn ó dìkàlẹ̀ , àgbà òṣèré Arígbábuwó parí eré sálákeji.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ọdẹ bá kú, ọdẹ níí sorò lẹ́yìn ọdẹ, báa bá sì kú làá di ère, èèyàn kìí sunwọ̀n láàyè, bẹẹ ni ọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ikú Olóyè Tóyọ̀sí Arígbábuwó tódágbére fáyé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dijọ ń siṣẹ́ tíátà ni wọ́n ti ń sàlàyé nípa irú èèyàn tí Arígbábuwó jẹ́ àti bó se lo ìgbé ayé rẹ̀ nígbà tó wà lókè eèpẹ̀ .

Nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́timọ́ Tóyọ̀sí Arígbábuwó tí wọ́n jọ ń siṣẹ́ tíátà, Alhaji Musiliu Dásọfúnjó sàlàyé pé Arígbábuwó jẹ́ akíkanjú èèyàn púpọ̀
Iṣẹ́ aránsọ ni Tóyọ̀sí kọ́kọ́ kọ́ nígbà ayé rẹ̀ kó tó yà sí ìdí iṣẹ́ tíátà, tó sì ń fi ẹ̀sà, ẹkún ìyàwó kéwì, èyí tí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí, kó tó wá dá ẹgbẹ́ tíátà tiẹ̀ sílẹ̀ táa mọ̀ sí Ẹgbẹ́ òṣèré Arígbábuwó. “Arígbábuwó Theather Group “ni àdúgbò Alekusọ-Oritamẹrin nílùú Ìbàdàn.

Olóògbé Sẹgun Olubukun, t’óun náà jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré orí itage ni ọ̀ga tó kọ́ Arígbábuwó ní isẹ́ tíátà.

Lẹ́yìn tí Arígbábuwó dá ẹgbẹ́ tíátà tiẹ̀ sílẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí ní se eré fún iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán ìjọba àpapọ̀ lásìkò tó wà ní WNTV kó tó wá di NTA báyìí.

Ó sì tún máa ń kéwì fún àwọn iléeṣẹ́ Redio káàkiri, paàpá ní Radio Nigeria tó wà nílùú Ìbàdàn tó fi mọ́ àwọn ètò mìíràn.

Tí a bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìhùwàsí olóògbé Arígbábuwó, Dásọfúnjó ní ó jẹ́ onísùúrù púpọ̀, tí kìí bá èèyàn kankan jà, tí ohunkohun kìí sì bí i nínú, paàpá nínú iṣẹ́ tíátà.

Dásọfúnjó sàlàyé pé 2018 ni Arígbábuwó kọkọ bẹ̀rẹ̀ àìsàn, tó sì se iṣẹ́ abẹ nílé ìwòsàn UCH, à mọ́ àìsàn yìí tún padà lọ́dún 2019, tó sì tún se iṣẹ́ abẹ fún ìgbà kejì, lẹ́yìn èyí sì ni kò leè jáde síta mọ́ títí tí ọlọ́jọ́ fi dé bá a.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà kó láti sèrànwọ́ fún Arígbábuwó lásìkò tó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, Dásọfúnjó ní òhun kò leè sọ pàtó ohun tí ẹgbẹ́ Tanpan àbí ANTP se láti ran Arígbábuwó lọ́wọ́.

À mọ́ ó ní ẹnikọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ Arígbábuwó ló dìde láti sa ipá tiẹ̀ fi sèrànwọ́ fún olóògbé náà.

Dásọfúnjó ní mánigbàgbé ni Arígbábuwó jẹ́ nínú iṣẹ́ tíátà, tó sì ti kọ́ ọ̀oọ̀ èèyàn nísẹ́ tíátà, kódà ọ̀kan lára wọ́n ti di Ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọgbà Fásitì báyìí.

Ó wá fọwọ́ gbáyà pé àwọn ti ń sètò láti dá àjọ aláànú kan sílẹ̀, táa mọ̀ sí Foundation lórúkọ olóògbé Tóyọ̀sí Arígbábuwó, èyí tí wọn yóó máa fi se ìrántí rẹ̀, kó má ba à parun.

Bákan náà, ọ̀rẹ́ minú mìíràn fún Arígbábuwó nínú iṣẹ́ tíátà, Gbọlagade Akinpẹlu, táwọn èèyàn mọ sí Ogun Majek náà sọ pẹ̀lú ẹ̀dùn pé , iṣẹ́ tíátà yé e dáa dáa , ó leè ṣeré, ó leè kọrin, tó sì tún leè kéwì

Ó ní Arigbabuwo jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́, tí kìí fa wàhálà lẹ́sẹ̀ àbí se ìjàngbọ̀n, tí àwọn yóó sì máa rántí rẹ̀ fún ọgbọ́n inú tó fi máa ń parí ìjà láàrin ẹgbẹ́ àti ọ̀nà àlàáfíà tó máa ń sán láàrin àwọn èèyàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …