Home ÀKỌ̀TUN Ìjo̩ba àpapò̩ lòdì sí ìdásílè̩ ‘Operation Àmò̩té̩kùn ‘
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 14, 2020

Ìjo̩ba àpapò̩ lòdì sí ìdásílè̩ ‘Operation Àmò̩té̩kùn ‘

Ìjo̩ba àpapò̩ lòdì sí ìdásílè̩ ‘Operation Àmò̩té̩kùn ‘
Láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Ijoba apapo orileede Naijiria ni eya kankan ko Leto lati da ajo idaabobo sile.
Minisita eto idajo,Alhaji Malami ni gbogbo eto aabo orileede gbodo wa lowo ijoba apapo. O ni ki iru nnkan bee to le waye, ijoba apapo gbodo fowo sii ni eyi to tumo si pe agbara ijoba apapo ko fe ka rogbodiyan ilu mo.
O ni pelu bi nnkan se ri lorileede yii bayii, ko tii si ohun to koja afarada. O ni ti ajo tabi eya igbogun ti aabo ilu ba tile fe fi agidi waye, ile Hausa ni ko ba fe lenu oro nitori wahala Boko Haram to n fojoojumo yo won lenu. O ni iyen gan-an ko ni awijare lodo ijoba apapo nitori pe ofin orileede yii ti odun 1999 ko fi aaye gba iru nnkan bee.
Malami tun ni iru eto isejoba ti a n se gan-an ko fara mo iru idasile bee.
Awon ara ilu si n reti ona miran ti awon gomina mefeefa tun fe gbe oro naa gba ti ijoba apapo fi maa gba a wole.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …