Home ÀKỌ̀TUN E ṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn òǹtàjà tí àjálù bá lọ́jà Akẹ̀sán fétò ìrànwọ́ …Makinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 13, 2020

E ṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn òǹtàjà tí àjálù bá lọ́jà Akẹ̀sán fétò ìrànwọ́ …Makinde

Ẹ ṣe àkójọpọ̀ orúkọ àwọn òǹtàjà tí àjálù bá lọ́jà Akẹ̀sán fétò ìrànwọ́ …Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìdùnnù ti ń ṣubú lu ayọ̀ bọ̀ fún àwọn òṣìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nítorí gómìnà Ṣèyí Mákindé ti kéde pé kò ní sí òṣìṣẹ́ kankan nípìńlẹ̀ Ọyọ tí owó rẹ̀ yóó kéré sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà, tíí se owó oṣù tó kéré jùlọ t’íjọba àpapọ̀ kéde rẹ̀.

Gómìnà Ṣèyí Mákindé sèlérí bẹ́ẹ̀ lásìkò ìsìn alájùnmọ̀ṣe àkọ́kọ́ láti kí ọdún tuntun 2020 káàbọ̀, èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sètò pẹ̀lú àwọn òṣìsẹ́, tó wáyé lọ́gbà Secretariat nílùú Ìbàdàn.

Gómìnà ní Ìjọba òun ti sèfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ kan tí yóó dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn òṣìsẹ́ lórí àgbékalẹ̀ owó oṣù tuntun náà pẹ̀lú àfikún pé ojú òpó kan náà ni ìjọba àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń tọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Bákan náà ni Mákindé fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé ìjọba òun kò ní mẹ́ẹ́rí nídìí ìpèsè ètò ìdrùn to yanranti fun awọn osisẹ ipinlẹ Ọyọ, eyi ti yoo mu igbe aye wọn bẹsuẹ si.

Ẹ̀wẹ̀, Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti se àbẹ̀wò sí ọjà Akẹ̀sán nílùú Ọ̀yọ́ tó jóná lọ́jọ́ Àìkú láti sàbẹ̀wò sí àwọn ohun tó jóná níbẹ̀.

Gómìnà Mákindé, ẹni tó bá àwọn èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí àti dúkìa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná náà kẹ́dùn, wá sèlérí pé òun yóó kọ́ ọjà ìgbàlódé padà fún wọn, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóó sì di Ilé ọba tó jó, ẹwà ló bù kun.
“Mo gba gbogbo ẹ̀bi mọ́ra lórí bí àwọn òṣìṣẹ́ panápaná se kùnà láti tètè bomi pa iná ọ̀hún kó tó bọ́wọ́ s’órí, Ìjọba mi yóó sì se àtúnṣe tó yẹ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Mákindé wá késí Álága afúnsọ́ Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà oòrùn Ọ̀yọ́, tí ọjà Akẹ̀sán wà lábẹ́ rẹ̀ láti se àkójọpọ̀ orúkọ àwọn òǹtàjà tí àjálù náà bá, lọ́nà à ti sètò ìrànwọ́ tó yẹ fún wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…