Home ÀKỌ̀TUN Oba Oluwo fárígá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àgbékalẹ̀ iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 11, 2020

Oba Oluwo fárígá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àgbékalẹ̀ iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni

Oluwo fárígá pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lórí àgbékalẹ̀ iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ni

Fẹ́mi Akínṣọlá

N tó dunni níí pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni,lọ̀rọ̀ Kábíyèsí Oluwo ti ìlú Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi dà báyìí o , bó ti kébòsí síta pé bí Ìjọba àpapọ̀ kò bá gbé iléẹ̀kọ́ olùkọ́ni onípò kínní tó fẹ́ dá sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọṣun sí ìlú Iwo, nǹkan yóó yan.

Ó ní pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ lèyí yóó jẹ́ fún àtìlẹ́yìn ribiribi tí àwọn èèyàn ìlú Ìwó ṣe fún Ìjọba ẹgbẹ́ Òsèlú APC.

Ọba Akanbi ní tí iléèwé gíga náà bá já mọ́ ìlú mìíràn lọ́wọ́ nìpínlẹ̀ Ọṣun, a jẹ́ wí pé òun yóó darapọ̀ mọ́ àwọn alátakò Ìjọba àpapọ̀ lórílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà ni.

Oluwo ṣàlàyé pé lára àwọn Ọbalaye tó dúró ti Ààrẹ Buhari ní gbangba lásìkò ìpèníjà rẹ̀, ọ̀kan gbòógì lòun jẹ́ nínú èyí tí òun ti ṣètò àwọn ìpàdé àdúrà ìtagbangba lórúkọ Ààrẹ, kí ìlera rẹ̀ leè túbọ̀ gbé ẹnu sókè.

Oluwo tún sọ ọ́ láìfọ̀tápè wí pé ní ojúmọ̀ tó mọ́ lónìí yìí, òun lòun lee darí omi àtìlẹ́yìn òsèlú àwọn èèyàn ìlú Iwo sí ibi tó bá wu òun.
Ó wá rọ asaájú ẹgbẹ́ òsèlú APC, Bọla Tinubu; Ìgbákejì Ààrẹ Yẹmi Oṣinbajo, Oloye Bisi Akande, Rauf Arẹgbẹṣọla pẹ̀lú Gómìnà Gboyega Oyetọla láti ríi dájú pé wọ́n gbé iléèwé náà kalẹ̀ sí ìlú Ìwó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…