Home ÀKỌ̀TUN Buhari kò leè du ipò fún sáà kẹta láyéláyé – Tinubu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 9, 2020

Buhari kò leè du ipò fún sáà kẹta láyéláyé – Tinubu

Buhari kò leè du ipò fún sáà kẹta láéláé…Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ , wọ́n ní abáni gbé mọ́ mọ́wà ẹni,…..
Bẹ́ẹ̀, ọrọ ìkọ̀kọ̀, ní gbangba ló ń bọ̀, èyí ló bí ìfèsì sí yunmu yunmu tí àwọn kan ń kù pe Ààrẹ Muhammadu Buhari àti Asíwájú Bola Ahmed Tinubu ṣèpàdé pọ̀ nílùú Abuja lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Lẹ́yìn ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ tó wáyé láàrin àwọn méjéèjì, Tinubu sọ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé asaájú Nàìjíríà náà jẹ́ oníwà rere àti onígboyà ènìyàn, tí kò sì leè fẹ́ se sá à kẹta lórí àlééfà láéláé.
“Àmọ́ Nàìjíríà tí orí rẹ̀ bá pé, tó bá sì ti bá Ààrẹ Muhammadu Buhari siṣẹ́ rí yóó mọ̀ pé kìí se ẹni tó leè ti ọwọ́ bọ òfin ilẹ̀ wa Nàìjíríà.

Àwọn èèyàn tí kò fẹ́ kó gbájúmọ́ iṣẹ́ tó ń se lórí ipò Ààrẹ, ló ń fura kiri, tí wọ́n sì ń fi àwọn ẹ̀sùn tí kò tọ́ kan Buhari, ṣùgbọ́n èmi ni mo ti ń jà fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjọba àwa ara wa.”

Alátakò ni mo jẹ́ tẹ́lẹ̀ fún Buhari kó tó di pé èròńgbà ṣíṣe sáà kẹta dé, èyí tí asaájú kan tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ yìí kùnà láti gbé kalẹ̀. Mo mọ Buhari pé kò leè gbìyanju irú rẹ̀ láéláé.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn …