Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ará ilú dáná sún èèyàn méjì tí wọ́n furasí bíi olè
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 9, 2020

Àwọn ará ilú dáná sún èèyàn méjì tí wọ́n furasí bíi olè

Àwọn ará ilú dáná sún èèyàn méjì tí wọ́n furasí bíi olè

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ gbogbo n t’olè, ọjọ́ kan n tolóhun.
Àwọn ènìyàn méjì kan ti wọ́n fura si gẹ́gẹ́ bi olè, ni wọ́n ti dáná sun nílùú Calabar, tíí ṣe olú ilú Cross River.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní agbègbè Akai Effa, tíwọ́n sì fi tipá fún àwọn afurasí náà ní fóònù láti pe àwọn ẹbí wọ́n láti sọ fún wọ́n pé, wọ́n ti fẹ́ dána sun wọ́n nítorí àwọn jalè .

Ìròyìn sọ pé, àwọn ará àdúgbò ọ̀hún pàmọ̀ pọ̀ láti dáná sún àwọ́n afurasí adigunjalè náà nítorí bí àwọn olè ṣe ń jà ládúgbò láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.

Ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì, afurasí ọ̀daràn kan lẹ́yìn tó jalè tán, tún fipá bá ẹni tó kámọ́lé lòpọ̀ ní agbègbè Okoro Agbor ní Calabar.

À mọ́ ó pàpà bọ́ sí ọwọ́ àwọn ará ìlú, wọ́n lùú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ sùgbọ́n ẹmi ti bọ́ lára rẹ̀ kí wọ́n tó gbé e dé ilé ìwòsàn

Alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Cross Rivers, DSP Irene Ugbo, fìdíi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, bí kò tilẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ míràn kún àlàyé rẹ̀ mọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…