Home ÀKỌ̀TUN Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì ọ̀bẹ bọ ara rẹ̀ náà níkùn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 8, 2020

Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì ọ̀bẹ bọ ara rẹ̀ náà níkùn

Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì ọ̀bẹ bọ ara rẹ̀ náà níkùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí òpin ayé bá ń bọ̀,onírúurú la á mọ rí. Ì bá má rí bẹ́ẹ̀ kín ló lé bí kí Pásítọ̀ Ìjọ kan ni Kenya gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́jọ́ àìkú lórí àga ìwàásù nínú sọ́ọ̀sì tí àwọn méjéèjì jọ dá a sílẹ̀ ní ìlú kan ní Mombasa.

Àwọn olùjọ́sìn tó wà nílé ìjọsìn lọ́jọ́ náà sọ fún àwọn oníròyìn pé Pásítọ̀ náà, Elisha Misiko jókòó níwájú nínú Ìjọ níbẹ̀ sì ló ti dìde lọ bá ìyàwó rẹ̀ lórí pẹpẹ tó sì gún un pẹ̀lú ọ̀bẹ tó fi pamọ́ sábẹ́ ẹ̀wù tó wọ̀.

Lẹ́yìn èyí ló lo ọ̀bẹ kan náà láti fi gún ikùn ara rẹ̀, bí àwọn ọmọ ìjọ ṣe tún fẹ́ sáré sí wọn lórí pẹpẹ ló fi ọ̀bẹ náà gé ara rẹ̀ ní ọ̀fun.

Lójú ẹsẹ̀ ni Elisha gbẹ́mìí mì nígbà tí ìyàwó rẹ̀ kú nílé ìwòsàn.

Ṣaájú kí ọ̀rọ̀ yìí tó ṣẹlẹ̀, tọkọ taya yìí ti ní aáwọ̀ lórí tani yóó máa ṣàkóso ìjọ gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìròyìn Daily Nation ṣe sọ ọ.

Gbogbo bó ṣe ṣẹlẹ̀ yìí làwọn tí ó ṣojú wọn kó rò fún àwọn oníròyìn nípa ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé pásítọ̀ yìí àti ìyàwó rẹ̀.

Arábìnrin kan ní ṣe ní kọ́ ń fi ìyà jẹ ìyàwó rẹ̀ tó bí ọmọ mẹ́rin fún un tó ń ṣe é báṣu bàṣu títí tí wọ́n fi pínyà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…