Home ÀKỌ̀TUN Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ránṣẹ́ pe àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 8, 2020

Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ránṣẹ́ pe àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ránṣẹ́ pe àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé iṣẹ́ Ààrẹ ti ránṣẹ́ pe àwọn gómìnà márùn un tó wà nílẹ̀ Yorùbá lórí àgbékalẹ̀ ètò ààbò ”Àmọ̀tẹ́kùn”” tí wọ́n fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ L’ọ́jọ́bọ.

Gbogbo ètò ló ti tò fún ìfilọ́lẹ̀ ètò náà eléyìí tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu jẹ́ alága rẹ̀.

Ìròyìn sọ pé, ilé iṣẹ́ Ààrẹ yóó ṣèpàdé nirọlẹ òní Ọjọ́rú pẹ̀lú àwọn gómìnà mẹfẹẹfa láti bèèrè Ìdí tí wọ́n fi fẹ́ fi ètò náà lólè nílẹ̀ Yorùbá.
Níbi àpérò kan tó wáyé lórí ètò ààbò lósù keje ọdún 2019, làwọn gómìnà mẹfẹẹfa ti pinnu láti gbé ètò Àmọ̀tẹ́kùn” kalẹ̀ lẹ́yìn ti ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé pọ̀ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá lọ́dún tó kọjá

Àwọn èèyàn tó ń ṣe Fijilanté, àwọn Onímọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ètò ààbò àtàwọn ọlọpaa yóó wà nínú ẹ̀ṣọ́ Àmọ̀tẹ́kùn” náà.

Ìṣẹ́ wọ́n ni láti máa ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ààbò káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, bákan náà ni wọ́n le mú àwọn ọ̀daràn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…