Home ÀKỌ̀TUN Lai Mohammed pe Yorùbá níjà

Lai Mohammed pe Yorùbá níjà

Iforo-wa-ni-lenu wo laarin Minisita eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed pelu Iroyin Owuro. Minisita ni ki a ma se gbagbe isese wa, Baba yii ni ki a fi gbogbo olaju gbe isese ati asa wa laruge.
Iroyin Owuro – Ki a maa baa maa fi gbogbo igba beere nipa oselu, eyin gege bii minisita asa ati ise. Ibo ni a gbe asa ile Yoruba de, paapaa julo abala iwosan?
Minisita – E see gan-an. Asise ti emi ati eyin n se ni Esin ti a n da po mo Asa. Asa ko ba esin je rara nitori pe opo ogbon ati oye lo po ninu asa wa ti o le se ebi ati ilu lanfaani.
E wo abala igbo mimu ati iwa ipanle to gbode kan bayii ko wopo laye atijo. Apejuwe ilu ti emi ti wa ni ilu Oro to wa ni ipinle Kwara. Ti eniyan ba gbe moto wale laye igba tiwa. Awon ebi maa wadii pe Lagbaja to gbe moto wale, ise kin ni o n se? Won a bi awon ore omo naa ki won to lo ba ebi. Ti awon ore ti won jo wa ni ilu kan naa ba ti ni ise eni naa ko mo, awon ara ilu maa tete ni ki ebi eni naa lee jinna. Eyi kii je ki awon omo le ya iyakuya Iaye atijo, nitori pe gbogbo omo lo ti maa mo pe ebi ko ni gba ise ti ko mo lowo awon. Adura gbogbo to lomo ni idale ni ki won “kere oko dele”. Nipa idi eyi, ko si eni to maa n fe ju sajo.
E tun je ki a wo abala Ekun iyawo, awon eko inu asa yii po gan an ni. Ibi ti arabinrin to fe lo ile oko ba ti n ko ewi yii ni o ti maa bere orisiirisii idanilekoo. Ibe ni won ti ma je ki o mo pe ile oko, ile eko ni, aponle fun baba oko ati iya oko, ki iyawo si mu won bii obi re, a kii laruko mo egbon oko ati aburo oko lori. Eyi ni kii je ki awon iyawo tuntun ni aye atijo laruko mo gbogbo awon ti won ba ba nile lori.
E tun je ki a wo aponle to wa ninu obinrin ti oko re ba nile laye atijo. Eyi naa maa n ko awon odobinrin lekoo pe awon gbodo para mo nitori abuku to wa nibe. Itiju nla ni eyi je fun obinrin ati ebi ti oko re ko ba ba nile laye atijo.
Iroyin Owuro – Ni abala iwosan, kin ni o ye ki a see?
Mnisita – Ise po ti gbogbo wa ni lati se nitori pe eri aridaju wa nibi iwosan aye atijo. Ojogbon Oyawole to je ore mi ni maa koko fi se akawe. Dunmomi loruko omo won ni igba naa. Ikun omo yii kan dede yo, won ti paara ile iwosan ti oro naa ko lojutu. Baba onisegun kan wa gbo ni ilu Ibadan lo ba bu oogun fun won ninu ikoko kan, o ni ti won ba ti dele ki won loo fun omo naa. Ni igba ti won dele, awon obi yii woju ara won pe pelu iwe ti awon ka, ki awon wa fun omo ni oogun ti awon ko mo ohun ti won po po sibe, Ojogbon yii ni igba ti o fi maa di ojo keji ti inira naa po ju fun Dunmomi ni awon ba bu koobu oogun yii fun un, bi o se muu tan ni o sun, ko pe ni o ji ti o si bere sip o gbogbo ohun to ti je tele, ni o ba tun sun, nigba ti o maa fi pada ji ariwo ebi ni Dunmomi n pa.
Ojogbon yii ba tun ni eyi mu ki inu awon dun ni awon tun bu die fun ni ojo keji ni eyi to tun mu ki o bi, Ojogbon ni ki awon to ti kilaasi de awon ti ba Dunmomi nita to n le Tata kiri, ikun re to wu ti lo sile. Omo ti a n soro re yii ti ni omoomo, ko si si ohun to jo aisan inu wiwu tabi foni ku, fola dide mo ninu gbogbo omo ati omoomo re.
Minisita ni ibi ti gbogbo wa ti jebi ni pe baba oloogun naa ti ku pelu oogun re. Bee sii ni ko tii si oogun kan pato to n wo arun “foni-ku, fola dide” (SICKLE CELL) doni.
Apeere miran ni ore mi kan to je omo Germany to wa ni akanse idanilekoo kan ni ilu Benin, Ore yii wa ni ofiisi ni igbaradi fun idanilekoo re ni o ni awon eniyan sakiyesi oju oun pe isoro kan wa. O ni bi oun se jewo niyen pe loooto ni o re aburo oun ni Germany. O ni aisan naa po de bi wi pe ese kan aye, ese kan orun lo wa. O ni bi won se mu oun lo si odo baba kan ni Benin niyi ti baba naa si ni se awon le gbe eni naa wa. O ni oun ni ko tile le soro bee ni ko le darin rara. O ni bi baba naa se ni ko si isoro niyen. O ba fun oun ni efun kan ati nnkan miran pe ti oun ba ti de Germany ki oun fi efun naa si iwaju ori aburo oun ki oun si fi ti ahon naa si ahon. O ni bi oun se se eleyii ni aburo oun laju ti o si n beere pe nibo ni oun wa ti awon si n da lohun pe ile iwosan ni nitori aare ranpe to see. O ni inu aburo yii dun ni eyi to si mu ki o yari pe oun ko se esin Kirisiteni mo doni . Gbogbo ohun ti mo n so nipa ore mi omo Germany yii ko tii ju oro osu kan lo.
Iroyin Owuro – Nibi ti oro wa de duro bayii, eyin gege bii Minisita asa ati ise, kin ni e n gbese?
Minisita – Gbogbo wa ni a ni lati dide si eleyii. Loju temi, o tile dabi eni pe igba ti awon Oyinbo koko de odo wa. Won koko ni ki awon baba wa lo da gbogbo nnkan iwosan won danu ni eyi to n se akoba fun wa lode oni. Ona abayo ni ki a tete gbaruku ti ibi ti o ba ku si.
Iroyin Owuro – E ku ohun sa, gege bi Minisita ati osise ijoba to lenu loro ni ilu, ipa wo le n ko ki awon asa ati awon eko ile ma baa parun ninu eto eko awon omo ode oni?
Minisita – E se pupo, awon nnkan yii ko see da se, a ni lati se ipade pelu ijoba ibile ati ipinle ki ise ijoba apapo to le yo. Eyi lo fi je wi pe ajo UNESCO (United Nations Educational, Scientific and Cultural Organization) mu eto eka ileese merin papo, eyi lo si faa ti awa bii merin fi maa n se ipade po lopo igba. UNESCO mu abala eto eko, o mu asa, o mu imo ero ati sayensi pelu abala eto iroyin ati asa. Igba yii ni a to le kese jari lori oro naa.
Iroyin Owuro – E ti so fun wa ri pe orin Dadakuada ti oloogbe Odolaye Aremu ni orin ti e feran ju. Kin ni o de sa?
Minisita – Ogbon ati oye ti o wa ninu awon orin naa ko see fenu royin tan. Mo tile tun gboo laipe yii nibi ti Odolaye Aremu ti korin ki Oloogbe Akintola. Awon ipede inu re ko lelegbe. Mo gbadun awon orin Dadakuada lopo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…