Home ÀKỌ̀TUN Àbá Àseyorí 2020

Àbá Àseyorí 2020

Gbogbo eyin alarojinle, e ku ojo meta. Eledua ko ni je ki a su ara wa. Awa ti a foju wina ipenija ilu yii naa lo maa je oro ilu naa lase Edumare.
Bi ere bi awada, odun 2019 keru nile, o maa di oro itan laarin wakati meloo kan si asiko ti a wa yi.
Odun tuntun yii, odun ara otun ni. Ibere dekeedi (Decade) awon oloyinbo ni. Odun mewaa gbako lo wa ninu re. Laarin dekeedi naa, opo milionia ati bilionia lo maa yoju. Opo to ti ni le maa ni mo nitori ojo ori tabi ki Eledua pe won sodo.
Eto idibo nla meji lo maa sele lati yan Aare, Gomina, Seneto ati awon asoju ni eyi to maa waye ni odun 2023 ati 2027.
Opo awon akekoo ile-iwe giga bayii lo maa pari Fasiti won ti awon miran maa gboye giga laarin odun mewaa naa. Opo wundia ati apon lo maa dalaya ati oloko pelu abiyamo.
Kin ni imurasile eyin alarojinle? Kin ni afojusun eyin eniyan mi gbogbo? Se e ranti pe eni ti ko ba dabaa ojo iwaju soro ba sore tabi ba rin. Iru awon eniyan bee ni Yoruba n pe ni alaropin, awon ni won ko ko ki ile ma se su ni aila (osan gangan). Se e ranti owe awon agba to so pe “eni to ba ran ara re lowo ni oosa oke naa n ran lowo”. Abi eyin wa ninu awon ti won Gbagbo pe “ohun to ba maa sele maa sele”. Awon eda yii ko ni ojo iwaju rara, won ko ni igbiyanju Kankan. Abi e wa ninu awon ti olori esin maa so bi e se maa lo igbesi aye yin? Nje e tile ranti iye odun ti won ti n tan yin bo? Se Olorun ni eyin tile n sin ni abi eniyan?
Eyin eniyan mi gbogbo, e je ki a ni alaale, ki a si maa roko tii nitori pe “ti a ba taa ti a ko too, iru eran bee maa n di eran onidin”. E je ki a wa fi adura ati igbagbo ninu Olorun kase re nile.
E ma se je ki a beru pupo nitori pe ile aye yi ko wa fun enikan. Ile aye ko si see da gbe. Ju gbogbo re lo “e ma se je ki a ta oja eepe, ki a ma baa gbowo okuta”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …