Home ÀKỌ̀TUN Ọdún 2020 máa burú ju 2019 lọ – Pastor Adeboye
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 6, 2020

Ọdún 2020 máa burú ju 2019 lọ – Pastor Adeboye

Yinka Alabi
Oludasile ile ijosin Redeemed Christians Church of God, Pastor E .A Adeboye lo n salaye nibi adura asewo odun 2020 ni olu ile ijosin won to wa ni opopona masose Eko si Ibadan.
Baba ni Olorun fi han awon pe a ni lati kun fun adura to po gan-an ni orileede yii ki isoro ati idaamu odun yii ma baa po ju ti odun ti o koja lo.
Baba Adeboye ni omo Naijiria ni lati gbadura fun idile won, ilu won ati orileede nitori pe odun yii yato patapata ninu awon ti a ti n lo bo.
Baba ni iyipada ijoba olokan-o-jokan maa waye kaakiri agbaye, ni eyi ti ohun naa nilo adura to po nitori wahala to sa pamo sibe naa po.
Ile riri, ile riru ati awon ajalu miran maa waye kaakiri awon orileede kan. Nipa idi eyi, a ni lati kun fun adura.
Pastor Adeboye ni ko si ohun to n da aye ru bayii to ju ese lo. Baba ni ese wa ti poju. Gbogbo nnkan ti oju ko gbodo ri ti eti ko gbodo gbo ni a ti so di nnkan ti a fi n yangan ni ode odi.
Baba ni eyi n mu ki inu maa bi Olorun, nipa di eyi, a ni lati tete kun fun adura ki a le ri iyonu Olorun pada. Ti a ba le tete jewo ese wa ti a si ronu piwada, ojo iwaju wa kun fun igbadun ati ayo. Pastor ni ti a ba le tete ronu piwada, ayo ati igbadun rerepe n be fun wa lojo iwaju paapaa julo awa ti a wa ni orileede Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…