Home ÀKỌ̀TUN Èmi sì máa kọrin lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún – Sunny Ade
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 6, 2020

Èmi sì máa kọrin lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún – Sunny Ade

Láti ọwọ́
Yínká Àlàbí
Oba orin, King Sunny Ade ni oun maa korin ku ni nitori pe ko see fi sile. O ni oun ti gbiyanju re ni igba kan ri ti awon ololufe oun ni Naijiria ati ni oke okun yari pe awon ko le gba. O ni won tile tun wa beere ibeere nla kan pe, kin ni oun fe maa se ti oun ba feyinti nibi orin? Sunny Ade ni ibe ni “apa oun ti jabo” pe ooto ma ni eleyii. Nigba ti opolo si n sise deede, ti agbara si wa, ti oun tun le ta Gita ti Eledua ko si gba ijo lese oun. O ni ju gbogbo re lo, oun ko tun mo ise miran dunju bi ise orin kiko.
Agba akorin Juju to ti le ni odun metalelaadorin, to si tun n ran bii okoto n salaye yii ni ilu Eko nigba ti odomodebinrin Temidara Onafuye n gbalejo re.
KSA ni oun ti se awo orin to le ni egberun meta (3,000) ti ko si si asadanu ninu won. O ni awon to n gboo nikan lo le ni eyi ti won yan laayo sugbon ni ti oun, gbogbo won ni ayanfe oun. Baba yii ni ife oun si orin ti bere lati pinnisin, nitori pe oun ko ju omo odun merindinlogun lo ti oun ti dogbon ra Gita pamo ninu owo ti oun te. O ni oun se eyi nitori awon obi oun ti ko fe ki oun fi orin kiko sise.
Oloye Sunday Adeniyi Adegeye ni oun dupe lowo Olorun lori igbega ninu orin naa. O ni aipe yii ni ajo kan lagbaaye ni oun ni oun se ipo kokandinlaadorin eni to mo gita (Guitar) ta ju. O ni gbogbo eleyiii pelu ife eyin ololufe wa lara iwuri oun nini orin naa. O ni ti oun ba ti fi orin sile, bawo ni iru omo odun mesan-an ileewe alakoobere North Caroline ni America, Temidara Onafuye se fe foriji oun.
Gbogbo irinajo KSA pelu Oloogbe Moses Olaiya ti gbogbo eniyan mo si “baba sala” lo salaye fun odomode yii. O wa dupe lowo awon obi omo naa bi won ko se je ki omo naa gbagbe ile. O ni ki won tubo maa fi ogbon ro Temidara bii aso. KSA ni oun ni lati pa awon ode kan ti fun omo naa nigba ti Alhaji Lai Mohammed tii se minisita eto iroyin ati asa salaye ife ti omode naa ni si oun.
Alhaji Lai Mohammed ati aya won, Alhaja Kudirat naa wa fi emi imoore han si Sunny Ade bi o se je ipe omoomo won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…