Home ÀKỌ̀TUN Dúkìá ṣòfò, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó lọ́jà Akẹ̀sán
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 6, 2020

Dúkìá ṣòfò, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó lọ́jà Akẹ̀sán

Dúkìá ṣòfò, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó lọ́jà Akẹ̀sán

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ dúkìa ló ti ṣòfò tí ọmọkùnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlà kan sì pàdánù ẹ̀mí rẹ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó jó ní ọjà Akẹ̀sán nílù Ọyọ.

Mọ́júmọ́ ọjọ́ Àìkú tíí ṣe ọjọ́ karùn ún, oṣù kínní ọdún 2020 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yí wáyé.

Nígbà tí ó ń fi Ìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn, alukoro ọlọpàá nípìńlẹ̀ Ọyọ, SP Fadeyi Olugbenga sọ pé ní nǹkan bí i aago méjì òru ni iná náà bẹ̀rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé kété tí àwọn gbọ́ ìro nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ni Ọ̀gá ọlọ́pàá lágbègbè náà pàwọn lọ síbẹ̀.

Ó ní: Ní Ìròyìn tó tẹ̀mí lọ́wọ́ kẹ́yìn, iná náà ti lọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò tí ì ríbi paná rẹ pátápátá.

Ọ̀gbẹ́ni Olugbenga sọ bákan náà pé àwọn agbófinró gbìyànjú láti gbógun ti àwọn tó le fẹ́ jí nǹkan gbé níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Olugbenga ni àwọn èèyàn kan dojú ìjà kọ , bóyá torí àwọn paná paná tí wọ́n ní wọn kò tètè dé láti pa iná náà.

Ṣùgbọ́n àwọn agbófinró ti paná ìfẹ̀hónúhàn náà.

Mo fẹ́ fi tó o yín létí pé kò sí òótọ́ nínú Ìròyìn pé àwọn ọlọpàá yìnbọn pa èèyàn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọ̀dọ́ kan ń dáná sun táyà nítorí pé àwọn paná paná kò tètè dé.

Àwọn wọ̀nyí àti àwọn tó fẹ́ yabo àgọ́ ọlọpàá la kọdi sí, tí a kò gbà láàyè. A kò yìnbọn mọ́ ẹnìkan kan”

Nígbà tí akọ̀ròyìn bèèrè lọ́wọ́ rẹ bóyá ẹnìkan kan kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ pé àwọn náà gbọ́ Ìròyìn pé ọta ìbọn ba ọmọkùnrin ọdún mẹ́rìnlà kan ṣùgbọ́n kìí ṣe ọlọ́pàá ló yìnbọn lù ú.
Ọ̀gá ọlọpàá ṣàlàyé pé àwọn ṣì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwádìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …