Home ÀKỌ̀TUN Ọlọ́pàá hú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ ṣekúpa
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 5, 2020

Ọlọ́pàá hú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ ṣekúpa

Ọlọ́pàá hú òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ ṣekúpa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hèèmọ̀ lukutu pẹ́bẹ́! Wọ́n tí ní bí òpin ayé bá ń bọ̀, onírúurú la ó máa rí. Ṣé a wá lé sọ pé tókú sinmi báyìí,bí
Ilé iṣẹ́ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Oṣun ti hú òkú akẹ́kọ́ọ̀bìnrin Fásitì ìpínlẹ̀ Eko LASU.

Ọmọbìnrin náà, Favour Daley-Oladele ń múra fún ètò àgùnbánirọ̀, kí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ kan tó jọ gbìmọ̀pọ̀ ṣekúpa á ní Ikoyi-Ile, ní ìpínlẹ̀ Oṣun.

Ọ̀gá ọlọpàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tó síwájú àwọn tó hú òkú náà, Babatunde Kokumo ṣàlàyé pé híhú òkú náà ṣe pàtàkì fáwọn ọlọpàá láti parí iṣẹ́ ìwádìí wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Pásítọ̀ Ìjọ aláṣọ funfun kan, Segun Philip àti Adeeko Owolabi tó jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin Favour pẹ̀lú ìyá a rẹ̀, Bola Oladele ni wọ́n ti wà ní gbaga Ilé iṣẹ́ ọlọpàá lórí ẹ̀sùn pé wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀ ni.
.
Pásítọ̀ Philip àti Owolabi jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ làwọn pa Favour láti fi ṣe òògùn owó, àmọ́ Ẹlẹ́dàá ọmọbìnrin náà kò jẹ́ ní òògùn owó
Nínú ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò wọn pẹ̀lú Adeeko ló ti ṣàlàyé pé pásítọ̀ fún òun ní ọmọ odo láti fi lù ú lórí tí pásítọ̀ sì sáré fi ọ̀bẹ yọ ọkàn rẹ̀, èyí tó fi se àṣèjẹ fun Adeeko àti ìyá rẹ̀.
Owolabi ẹni ọdún mẹ́tàlélógún náà sọ pé òun kábàámọ̀ ọ ohun tí òun ṣe pẹ̀lú Philip. Ó ní iṣẹ́ tó bọ́ lọ́wọ́ bàbá àti m màmá òun ló sún òun débi fífi ọ̀rẹ́bìnrin òun ṣe òògùn owó.
Ẹ̀wẹ̀, bàbá olóògbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin náà sàpèjúwe Favour gẹ́gẹ́ bí wúrà nínú ìdílé òun.
Bàbá Favour ní: ”A wojú Ọlọ́run fún ọdún díẹ̀ kí á tó bí Favour.

Ó sì lọ Fásitì èyí tó mú inú wà dùn pé yóó kẹ́kọ́ọ̀ gboyè láìpẹ́ ṣùgbọ́n èèyàn kan gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣekúpa á,”

Bàbá olóògbé náà ní Ikú Favour jẹ́ ìbànújẹ́ ńlá fún ìdílé òun àti pé ìdájọ́ òdodo nìkan ló kù tí òun ń retí. À fi kí Aláwùràbí rọ bàbá Favour lójú ló kú báyìí o . À bí ìwàásù wo ló kù féèyàn tí ìkookò ayé pa lọ́mọ́ jẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…