Home ÀKỌ̀TUN Àwa ò gbọ́ pé Fúlàní darandaran gbé wa re ilé ẹjọ́ o – Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 4, 2020

Àwa ò gbọ́ pé Fúlàní darandaran gbé wa re ilé ẹjọ́ o – Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ

Àwa ò gbọ́ pé Fúlàní darandaran gbé wa re ilé ẹjọ́ o… Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ní àwọn kò gbọ́ pé ẹgbẹ́ Fúlàní darandaran kankan ní ìpínlẹ̀ náà gbé àwọn lọ sí Ilé ẹjọ́.

Èyí kò ṣẹ̀yin ìròyìn tó tàn kálẹ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ Fúlàní Darandaran, “Gan Allah Fulani Development Association of Nigeria”,ti gbé Ìjọba lọ sí Ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fi òfin tuntun de kíkó màálù jẹ̀ káàkiri ìlú, eléyìí tí wọ́n ní ó tẹ ojú ẹ̀tọ́ àwọn mọ́lẹ̀.

Adarí ètò ìròyìn fún Gómìnà Mákindé, Taiwo Adisa ló fi léde bẹ́ẹ̀ pé ohun tí àwọn gbọ́ ni wí pé àwọn ẹgbẹ́ darandaran kan ń fapá jánú lórí òfin tuntun tí àwọn ṣe lórí ètò ọ̀gbìn ní ìpínlẹ̀ náà.
Adisa fikún un pé òfin náà kò tẹ ẹ̀tọ́ wọn lójú mọ́lẹ̀, bí kìí ṣe kí ètò ọ̀gbìn le gbòòrò si ni àwọn ṣe ṣe òfin náà bẹ́ẹ̀ Ilé Aṣòfin ìpínlẹ̀ sì gbé e yẹ̀wò, kí wọ́n tó wá buwọ́ lù ú.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ó ní àwọn ti tọ àwọn Fúlàní darandaran lọ láti gbé òfin tuntun náà yẹ̀wò , tí wọ́n sì wò ó fínífíní, kí ó tó di wí pé wọ́n fòǹtẹ̀ lu òfin náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìjọba ìpínlẹ̀ ló ti gbé òfin dida ẹran dìde káàkiri yẹ̀ wò nítorí ètò ààbò tó dẹnukọlẹ̀ àti ìjàmbá tó ń ṣe fún ètò ọ̀gbìn ní àwọn agbègbè kan lórílẹ̀-èdè-ede Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …