Home ÀKỌ̀TUN Mu pàrágá wakọ̀ l’Ọyọ, kóo kó sí páńpé̩ ìjọba
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 31, 2019

Mu pàrágá wakọ̀ l’Ọyọ, kóo kó sí páńpé̩ ìjọba

Mu pàrágá wakọ̀ l’Ọyọ, kóo kó sí gbaga ìjọba

Fẹ́mi Akínṣọlá

Omi tuntun ti rú, ẹja tuntun ti wọ ọ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Awakọ̀ mẹẹdọgbọn ni ọwọ́ òfin ti tẹ̀ nìpínlẹ̀ náà lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń mutÍ nígbà tí wọ́n tún ń wa ọkọ̀.

Kọmíṣọ́nnà fún ètò Ìròyìn nípìńlẹ̀ náà, Wasiu Olatubosun tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàye pé ìgbésẹ̀ yìí yóó jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn awakọ̀ míì tí wọ́n bá tún fẹ́ hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ .

Lópin ọ̀sẹ̀ tó lọ ni àjọ tó ń rí sí ìdarí ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, OYRTMA mú àwọn awakọ̀ náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé tó le ṣàfíhàn bí èèyàn bá mu ọtí.
Kọmíṣọ́nnà Olatubọsun sọ pé gbogbo àwọn awakọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n náà ni yóó fojú ba Ilé ẹjọ́.

Kọmíṣọ́nnà ní Ilé ẹjọ́ ni yóó sọ pàtó ìjìyà tó tọ́ sí wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Olatubosun tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé mímú àwọn awakọ̀ tó ń mu ọtí kìí ṣe nínú àsìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún nìkan.

Kọmíṣọ́nnà fún ètò Ìròyìn nípìńlẹ̀ Ọyọ ní ètò náà yóó tẹ̀síwájú nínú ọdún 2020 nítorí ẹ̀mí àwọn èèyàn ìpínlẹ náà jẹ ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé lógún.

Ẹ̀wẹ̀, Álága OYRTMA, Dókítà Akin Fagbemi ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ àjọ wọn láti mú àwọn ọmuti awakọ̀ wa ni ibamu pẹlu iṣẹ ajọ naa lati dẹkun ijamba ọkọ tawọn ọ̀mùtí awakọ̀ ń ṣe ṣokùnfà rẹ̀ nípìńlẹ̀ O Ọyọ.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ní òpópónà Ring-Road, Iwo-Road, àti Mọ́níyà sí Ogbomoṣo ni ti múwọn àwọn awakọ̀ ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…