Home ÀKỌ̀TUN Ohun t’ọ́kùnrin ń ṣe l’Ekiti, obìnrin lè ṣe é.. Àjọ̀dún Àṣà ìbílẹ̀ lékìtì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 30, 2019

Ohun t’ọ́kùnrin ń ṣe l’Ekiti, obìnrin lè ṣe é.. Àjọ̀dún Àṣà ìbílẹ̀ lékìtì

Ohun t’ọ́kùnrin ń ṣe l’Ekiti, obìnrin lè ṣe é.. Àjọ̀dún Àṣà ìbílẹ̀ lékìtì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àṣà àti ìṣe wà nínú n tíí ṣàfíhàn èèyàn bí ọmọ ọkọ tàbí ọmọ ìdàkejì n ló díá fún bí onírúurú ohun tẹ́ ẹ̀ tilẹ̀ mọ pé ó wà láyé yìí se dohun àfojúrí níbi ayẹyẹ àjọ̀dún àṣà ọdún yìí ní ipinlẹ Èkìtì, .

Adarí iléeṣẹ́ Àṣà ni ìpínlẹ̀ Èkìtì, Wale Ojo sọ fún akọ̀ròyìn pé àwọn ń kó àwọn àṣà àwọn jáde láti ṣe àfihàn rẹ̀ fáráyè ni.

“A sọ ijó di owó, ohun t’ọ́kùnrin ń ṣe l’Èkìtì, obìnrin lè ṣe é”. Ọ̀gbẹ́ni Wale sọ pé Èkìtì Festival ti mú ọlá àti oríire wọ ìlú Èkìtì, “ó ń gbe ọgbọ́n inú àti ìmọ̀ àwọn ọ̀dọ́ jáde síta”.

Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo ìlú tó wà ní Africa ló kù tí Èkìtì máa fìwé pè lọ́dún 2020 láti wá wo ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye ti Ọlọ́run fi sọlọ̀ sí ìlú Èkìtì.

Lóòtọ́ lóòtọ́, kò sí àṣàdànù nínú àwọ́n afihan ohun agbaṣa ga to waye nibi EKiti Festival 2019.

Ṣé ẹ mọ̀ pé Ekiti ni ìlú tí Ògún Lákááyé wọlẹ̀ sí?
Ìlú Ọrúnmìlà náà, Èkìtì ni.

Èṣù tó má a ń dá àbò bo àwọn èèyàn tirẹ̀, Èṣù Ẹlẹ́gbára tó máa ń gba àwọn eeyan lọ́jọ́ ibi bá dé, ìlú Ekiti ni gbogbo wọn ti wá gẹ́gẹ́ bí adarí àṣà ìpínlẹ̀ náà ṣe sọ ọ́.

Ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Erelú Bísí Fáyemí kádíì ètò àjọ̀dún náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Ekiti pé “Orin Ekiti dá yàtọ̀, ijó wọn, òkè ńlá ńlá àtàwọn nǹkan tó jẹ́ pé owó làwọn èèyàn fi lọ ń wò wọ́n níbòmíràn”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …