Home ÀKỌ̀TUN Àso̩té̩lè̩ f’ó̩dún 2020 – Primate Ayo̩dele
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 28, 2019

Àso̩té̩lè̩ f’ó̩dún 2020 – Primate Ayo̩dele

ASOTELE F’ODUN TO N BO LATENU PRIMATE AYODELE TUN YANI LENU O!
Yinka Alabi
Ninu poposinsin odun keresimesi to koja ni iranse Olorun alaaye nni to tun je ariran,Primate Babatunde Elijah Ayodele to ni ijo INRI Evangelical Spiritual Church lagbegbe Oke Afa l’Ejigbo nipinle Eko,ti soro nipa die ninu awon ooto to yani lenu ti yoo sele ninu odun 2020 nipa Naijiria,awon adari wa atawon omo ilu yii to wa loke okun.Nipa tawon eeyan wa to wa lajo lohun,Primate Ayodele kesi gbogbo eeyan lati kun fun adura nitoripe opolopo wahala ati aibale okan ni yoo bawon lohun,ti awon ijoba oke okun yoo si da oke aimoye pada silu baba won nibi.Orileede Naijiria la gbo pe oro aje re yoo kun opolopo ifaseyin to si je pe ipa awon adari wa tabi eto isuna yoo ka a.Iranse Olorun Ayodele tun pe fun ebe adura lati da iku opolopo awon eeyan pataki to ti ran orileede yii lowo ri bee lo tun so asotele re pe itaporogan yoo wa laarin eya Yoruba sa’Hausa ati laarin eya Ibo sa’Hausa bakan naa.Opolopo omo Naijiria la gbo pe
yoo ri ewon he tabi jebi iku latari lilu ofin ‘oo gbodo f’ehonu han’
t’ijoba ti n je lenu lojo to ti pe.Lori eto aabo,Ojise Olorun Ayodele
dahun pe ko ni si iyipada ninu oro aabo to mehe atipe opolopo ibi
pataki lorileede yii ni yoo fara gba a.Agbara ojo to buru jai ni yoo
sele lawon ilu bii Enugu,Kogi,Eko,Ondo ati Ekiti bi awon eeyan agbegbe
yii ko ba kun fun adura.O ke s’Aare orileede yii,Mohamadu Buhari lati
kiyesara gidigidi ninu apata agbara to wa lohun bee lo tun ro o lati
moju to ilera re daada lodun 2020.Igbakeji aare,Yemi Osinbajo paapa
yoo koju isoro nla pelu oga re nitoripe awon kan yoo petepero lati yo
o danu bi ko ba kun fadura.Asiwaju Bola Ahmed Tinubu naa gbodo bere
aawe at’adura bayii ki awon to n pe ni ololufe e ninu egbe oselu APC
ma baa da a lagbo nu lairotele ninu odun tuntun bee laje iwa ibaje ati
is’owo ilu kumokumo yoo tun si mo opolopo lori.Nipari,Primate B.E
Ayodele ro gbogbo olujosin lati mb gbadura dipo ifoya lori awon
asotele iberu ohun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…