Home ÀKỌ̀TUN Mánigbàgbé eré bó̩ò̩lù – Atlanta 1996
ÀKỌ̀TUN - ERÉ ÌDÁRAYÁ - orisiirisii - Orisirisi - December 24, 2019

Mánigbàgbé eré bó̩ò̩lù – Atlanta 1996

Manigbagbe boolu “Atlanta 1996”
Yinka Alabi

Ere boolu yii waye ni odun naa nigba ti Oloogbe Sani Abacha n tuko orileede yii.
Bonfere Jo ni akonimoogba, Kanu Nwankwo si ni olori awon agbaboolu.
Gbogbo igba ni iko Super Eagles maa n je iya lowo orileede Brazil. Ti ojo naa tun ti ri bi o ti maa n sabaa ri. Brazil to gba ayo meta wole gege bii ise won nigba ti orileede Naijiria da okan pada titi di iseju metadinlogorin idije naa.
Iko agbaboolu Brazil pe pelu awon oruko nla bii Carlos, Rivaldo, Bebeto, Ronaldo ati bee bee lo.
Laarin emi ati eyin, iyalenu sele nigba ti Victor Ipeba gba keji wole, Kanu fi ijeeta si inu ile won.
Eyi mu ki ere boolu naa wa gbona janjan. O ti wa di “eni ori yo, o dile”. Iko to ba koko gba boolu wole alatako re lo bori ni igba naa. Ki a to seju pere, Kanu Nwankwo ba fi oba lee. Bi orileede Naijiria se jawe olubori nigba naa ya gbogbo aye lenu.
O ya, e je ki a wo ere boolu odun kerinlelogun naa bi boolu ana…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…