Home ÀKỌ̀TUN Ẹ di ẹ̀bi rògbòdìyàin Kogi ru ìwà kòtọ́ àwọn olóṣèlú – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 17, 2019

Ẹ di ẹ̀bi rògbòdìyàin Kogi ru ìwà kòtọ́ àwọn olóṣèlú – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Ẹ di ẹ̀bi rògbòdìyàin Kogi ru ìwà kòtọ́ àwọn olóṣèlú..Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ààrẹ ti ṣọ saájú pé kí àwọn olùdíje àti àtẹ̀lé wọ́n ó sohun gbogbo pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run lásìkò ìdìbò Kogi àti Bayelsa,síbẹ̀,iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kò dín ní èèyàn méjìlélógún tí ọwọ́ tẹ̀ lórí rògbòdìyàn tó wáyé lásìkò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Kogi.
Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Frank Mba ló sàlàyé ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó fi ń sọ̀rọ̀ lórí iléeṣẹ́ móhùnmáwòrán abẹ́lé kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lálẹ́ ọjọ́ Sátidé lẹ́yìn tí ìbò dídì parí láwọn ìpínlẹ̀ méjéèjì.

Bákan náà ló ní ọkọ̀ kan táwọn jàǹdùkú fẹ́ fi hùwà láabi lágbègbè kan ní Kogi lọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tún tẹ̀.
Ó fi kún un pé àìmọye onínírúurú ìbọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọta ìbọn ni wọ́n tún gbà lọ́wọ́ àwọn ọ̀dàlúrú kan ní Ìpínlẹ̀ náà.

Ọga ọlọpaa Frank Mba ní àwọn olóṣèlú pẹ̀lú ìwà bóo bá a o pá, bóòba o bùú lẹ́sẹ̀ àti ìwà àfèmi-àfèmi wọn ló fa gbogbo rúkèrúdò tó wáyé lásìkò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ méjéèjì, papàájùlọ nípìńlẹ̀ Kogi.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kò sí àníàní pé ètò ìdìbò Gómìnà nípìńlẹ̀ Kogi gbomi lára àwọn agbófinró ju ti ìpínlẹ̀ bayelsa lọ.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà ní lóòtọ́ ni àwọn ṣe ìfimúfínlẹ̀ tó múnádóko ṣaájú ìdìbò náà láti mọ ibi tí èéfín wàhálà leè ti rú lásìkò ìdìbò náà síbẹ̀ ohun tó wáyé kìí ṣe èyí tí wọ́n leè máa dẹ̀bi rẹ̀̀ ru àwọn agbófinró bí ó ti wù ó mọ. Ó ní ká ní kìí ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kò bá burú ju bí ó ti rí náà lọ.

Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí iye èèyàn tó kú lásìkò ìdìbò ní Ìpínlẹ̀ Kogi, lẹ̀yìn tí ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn mẹ́ta làwọn afurasí jàǹdùkú kan tí wọ́n wọ aṣọ ọlọ́pàá yìnbọn pa lásìkò ìdìbò náà, alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà náà ní òun kò tíì le sọ ní pàtó iye àwọn èèyàn tó pàdánú ẹ̀mí wọn lásìkò ìdìbò náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …