Home ÀKỌ̀TUN Ẹni tó bá kàwé leè di Ààrẹ, dandan kọ́ ni ìwé ẹ̀rí – Àwíjàre ilé ẹjọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 16, 2019

Ẹni tó bá kàwé leè di Ààrẹ, dandan kọ́ ni ìwé ẹ̀rí – Àwíjàre ilé ẹjọ́

Ẹni tó bá kàwé leè di Ààrẹ, dandan kọ́ ni ìwé ẹ̀rí – Àwíjàre ilé ẹjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sọ pé, Ààrẹ Muhammadu Buhari yẹ láti díje sípò Ààrẹ orílẹ̀-èdè-yii, ló jẹ́ kí òun da ẹjọ́ Atiku Abubakar nù.

Ilé ẹjọ́ náà ní òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ díje sípò Ààrẹ gbọdọ̀ kàwé, ó kéré jù, kó lọ sílé ìwé girama.
Ó ní ohun tí òfin sọ ni pé kí ẹni náà kàwé, yálà ó ní ìwé ẹ̀rí tàbí kò ní ìwé ẹ̀rí.
Ilé ẹjọ́ ọ̀hún sọ pé, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe gbé e kalẹ̀, ẹni tí ó bá ka ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, tó le kọ, tó sì le kà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì le díje nínú ìdìbò.

Nínú ìdájọ́ náà tí adájọ́ àgbà lórilẹ̀-èdè yìí, Tanko Muhammad kọ, tí adájọ́ John Okoro kà sọ pé, ẹjọ́ tí olùdíje sípò Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ PDP, Atiku Abubakar pè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Lẹ́yìn náà ló fòǹtẹ̀ lé ẹjọ́ tí Ilé ẹjọ́ tó ń gbẹ́sùn ìdìbò dá ṣaájú pé, Muhamadu Buhari ní ojúlówó ẹni tó borí nínú ìdìbò Ààrẹ lọ́dún 2019.

Ó tẹ tẹ̀síwájú pé, Ààrẹ Buhari kò parọ́ fún àjọ INEC nípa ipele ìwé tó kà.
Ilé ẹjọ́ ọ̀hún tún ní, olùdíje lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ PDP kò fi Ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, itàkùn ayélujára tó ti rí èsì ìdìbò náà jẹ́ ti àjọ elétò ìdìbò tàbí kìí ṣe ti àjọ INEC
Àti pé Atiku kùnà láti fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé àìse déédé wà lásìkò ìdìbò náà àti pé wọ́n dìbò tayọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…