Home ÀKỌ̀TUN A ṣetán láti fìyà tó tọ́ jẹ ọmọ ogun tí aje ìwà ìbàjẹ́ fídíò náà bá ṣímọ́ lórí… llé isẹ́ ológun Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 4, 2019

A ṣetán láti fìyà tó tọ́ jẹ ọmọ ogun tí aje ìwà ìbàjẹ́ fídíò náà bá ṣímọ́ lórí… llé isẹ́ ológun Nàìjíríà

A ṣetán láti fìyà tó tọ́ jẹ ọmọ ogun tí aje ìwà ìbàjẹ́ fídíò náà bá ṣímọ́ lórí… llé isẹ́ ológun Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Láàrín òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni fídíò kan jáde lórí ayélujára tó ṣàfihàn àwọn ọmọ ogun kan tó hùwà tí kò bá ìlàsílẹ̀ iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ mu.
Ilé iṣẹ́ ọmọ ogun ní àwọn kò ní fọwọ́ ra ọmọ ogun tí igbá ìwà ìdájọ́ lọ́wọ́ ara ẹni bá ṣí mọ́ lórí rárá.
Èyi jẹ́ èsì lórí fọ́nrán kan tó ń tàn ká lórí ayélujára bí àwọn ọmọ ogun kan se pa afurasí Boko haram tí wọ́n sì sin ín sí sààre tí kò jinlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Borno ní àríwá ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ fi àtẹ̀jáde síta lórí ìpinnu wọn lẹ́yìn ti wọ́n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìwà ipá náà pé kò bá òfin àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà mu.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Nàíjíríà ní wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí ní kíkún lórí fídíò náà àti àwọn tó wà níbẹ̀ nítorí pé ìwà tí wọ́n hù lòdì sí iléeṣẹ́ omo ogun , ó sì tún tàbùkù wọn.
Ọ̀gágun àgbà Sagir Musa tó jẹ́ adelé adarí agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ omo ogun ilẹ̀ sọ pé ìwà náà lodi si òfin Nàìjíríà.
Sagir ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ ogun láti máa ṣọ́ra ṣe paàpá nígbà tí inú bá ń bí wọn tàbí tí nǹkan ṣẹlẹ̀, kí wọ́n má baà tẹ ojú ẹ̀tọ́ ará ìlú mọ́lẹ̀.
Ó ní wọ́n ti mọ̀ pé ìjìyà tó tọ́ wà fún ẹnikẹ́ni tó bá hùwà àìtọ́ nínú àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …