Home ÀKỌ̀TUN Agbas̩é̩s̩e kankan kò gbo̩dò̩ mówó è̩yìn dó̩dò̩ mi – Seyi Makinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 2, 2019

Agbas̩é̩s̩e kankan kò gbo̩dò̩ mówó è̩yìn dó̩dò̩ mi – Seyi Makinde

Gómìnà Ọ̀yọ́ pàṣẹ kí wọ̀n dáwọ iṣẹ́ dúró lórí iṣẹ́ àgbàṣe ₦67bn òpópónà Ibadan sí Eko.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pàṣẹ kí àwọn kọngílá tó ń ṣiṣẹ́ lórí òpópónà olóbìírípo ‘Ibadan Circular road ” eléyìí tí àwọn awakọ̀ le má a gbà dípò ojú ọ̀nà márosẹ̀ Eko ṣílùú Ibadan láti dáwọ́ iṣẹ́ dúró.
Gómìnà Seyi Makinde ló pàṣẹ yí lásìkò tó ń sàbẹ̀wò láti mọ bí iṣẹ́ ti ṣe n lọ sí lọ́nà náà.
Makinde ní Ìjọba yóó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn kọngílá tí wọ́n gbé iṣẹ́ náà fún láti lé mọ ọ̀nà táwọn yóó fi wá owó iṣẹ́ náà torí pé òpópónà yìí ṣe pàtàkì sí ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Oyo.
Kìlómítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni ọ̀nà náà jẹ́ tí wọ́n sì ya bílíọ̀nù méjìlélọ́gọ́ta kalẹ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀.
Makinde sọ fáwọn oníròyìn pé ìdá márùn-ún lé díẹ̀ nínú ìdá ọgọ́rùn un iṣẹ́ náà ni wọ́n ṣẹṣẹ ṣe.
Ọ̀rọ̀ owó lórí iye tí wọ́n yá fún iṣẹ́ náà ti ń mú kí ominú máa kọ àwọn èèyàn lórí iye náà.
Láìpẹ́ sí ìgbà tó gun orí àléfà ló sọ pé agbaṣẹ́ṣe kankan kò gbọdọ̀ mú owó ẹ̀yìn wá bá òun bí wọ́n ti ṣe ń ṣe pẹ̀lú ìjọba tó kọjá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …