Home ÀKỌ̀TUN E̩nu bode kò wà ní títì pátápátá – Hameed Ali
ÀKỌ̀TUN - iroyin - orisiirisii - Orisirisi - October 30, 2019

E̩nu bode kò wà ní títì pátápátá – Hameed Ali

E̩nu bode kò wà ní títì pátápátá – Hameed Ali
Lati owo
Yinka Alabi
Ajo asobode ile wa ti gbogbo aye mo si Customs ni won tun ti gbese le awon oja to lodi sofin ti owo re le ni milionu meji naira.
Ibi ti oga patapata ajo naa ti n ba awon oniroyin soro lo ti salaye pe ijoba “ko ni gbo, bi awon onifayawo naa se ni awon ni gba”.
O ni gbogbo oja ti ijoba ti fofin de ni awon onisowo yii si n ko wole. O ni owo ofin ti te apo iresi ti ojo ti lo lori re repete, bee naa ni oogun to ti baje, ororo ati awon nnkan ipara miran.
Ibe naa ni oga naa tun ti n salaye pe ijoba ko ti bode tan patapata, o ni ijoba si fi aaye gba awon to fe wole ati jade ni ona eto. O ni nipa ti eru, titi gbain-gbain ni awon bode Naijiria wa.
Hammed Ali ni oro naa ko si le rara ti awon orileede ti a jo paala ba le tele awon alaale orileede Naijiria.
O ni eyi lo le je ki asepo to dan moran wa laarin orileede. O ni “o to ge” orileede Naijiria ko le di akitan fun awon aladugbo wa. O ni awon kan ko le maa fi Naijiria pawo si apo ara won nikan. O ni ki won je ki awon jo jokoo yoo si otun ati si osi ni eyi to le seso rere fun onile ati alejo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…