Home ÀKỌ̀TUN O le gba ìwé ìrìnnà (Visa) láti wá fẹ̀yìntì sí Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 29, 2019

O le gba ìwé ìrìnnà (Visa) láti wá fẹ̀yìntì sí Nàìjíríà

O le gba ìwé ìrìnnà (Visa) láti wá fẹ̀yìntì sí Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ilé iṣẹ́ ìrìnà lorilẹ-ede Nàìjíríà ní àwọn ti setán láti gbé orisirisi ìwé ìrìnà tuntun jáde fún àwọn ènìyàn.
Adarí ilé iṣẹ́ ìrìnà náà, Mohammad Babandede ló sọ ọrọ yìí níbi ìpàdé àwọn Ọ̀gá Àgbà ìrìnà tó wáyé ní Benin, lorilẹ-ede Nàìjíríà.
Babandede ní àwọn ẹka tí yóò má a gba ìwé ìrìnnà náà, ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wá gbafẹ, àwọn tí wọ́n fẹ́ wá se káràkátà àti àwọn tí wọ́n fẹ́ wá fẹyìntì sí orilẹ-ede Nàìjíríà.
Èyí túmọ si wí pé Nàìjíríà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún àwọn ènìyàn tó wà ní ilẹ̀ òkèrè, tí wọ́n fẹ́ wá fẹyìntì sí orílẹ̀èdè Nàìjíríà ní Ìwé Ìrìnnà.
Osu Kefa, ọdun 2019 ni Naijiria bẹrẹ si ni lo iwe irinna to n lo ẹrọ ayelujara, eléyìí ti yóò faye gba àwọn ènìyàn láti lo ìwé ìrìnnà wọn fún ọdún mẹ́wàá, ó sì tún le wòye ibi tí ènìyàn wà ní ìgbà dé ìgbà.
Ìwé ìrìnnà náà pín sí ọ̀nà mẹta, ìkan fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, ìkan fún àwọn òṣìṣẹ́ pàtàkì àti ìkẹta fún áwọn òṣìṣẹ́ pàtàkì fún ìjọba Nàìjíríà.
Ọdun 2018 ni ọga ilé iṣẹ́ ìrìnnà Nàìjíríà sọ wí pé Oṣù Kejìlá, ọdún 2018 ní àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ìwé ìrìnnà tuntun náà.
Àmọ́, ó fikún un wí pé àwọn tó ní ìwé ìrìnnà ti tẹ́lẹ̀ náà yóò ní àǹfààní láti lò ó, láì sí ìdíwọ ìdènà kankan.
Bákan náà ni Ọ̀gá Àgbà ilé iṣẹ́ Ìrìnnà Nàìjíríà náà fikún un wí pé ipa rere ni ibodè Nàìjíríà ti kó lórí ọrọ̀ ajé orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti wíwọlé-wọde àwọn ènìyàn láti orílẹ̀èdè mìíràn wá sí Nàìjíríà.
Ọ̀gá Mohammad Babandede fikún-un wí pé ó lé ní ẹgbẹrun mọkanla ènìyàn tí ọwọ́ ti tẹ lásìkò tí wọ́n wá ọ̀nà láti kúrò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láì ní Ìwé Ìrìnnà tó péye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…