Home ÀKỌ̀TUN Ìdí ààbò àwọn Ìmáàmù ni Mecca rè é
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 27, 2019

Ìdí ààbò àwọn Ìmáàmù ni Mecca rè é

Ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Ìmáàmù ni Mecca rè é

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ awuyewuye ló ti ń wáyé tí ọ̀pọ̀ ń bèèrè ìdí tí àwọn ọmọ ogun ilẹ fi ń ṣọ́ àwọn aafa tó ń ṣaájú ìrun ní Mẹka àti Medina.
Látàrí èyí ni àwọn aláṣẹ mọṣalaṣi méjèèjì fi sọrọ lójú òpó facebook wọn tí wọ́n sì ṣàlàyé ní kikun ohun tó ṣokùnfa ìgbésẹ̀ yìí.
Àwọn èèyàn ń bèèrè pé ṣé ó yẹ kori bẹẹ, kódà lásìkò ti awọn aafa yii ba n pe irun ninu mọṣalaṣi.
Wọ́n ní àwọn kò déédé gbé ìgbésẹ̀ yìí bíkòṣe láti pèsè ètò ààbò tó péye fáwọn Imaam náà ni.
Àwọn aláṣẹ náà mẹnuba àwọn kókó wọ̀nyí pé, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ lọ́dún-un 2015 nígbà tí ọkùnrin kan ṣàdédé ń pariwo lé aafa Sheik Ali Al Hadaify lórí lásìkò tó ń pe ìrun lọ́wọ́ nínú mọṣalaṣi ńlá náà.
Yàtọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ tọdún 2015, lọ́dún-un 2011 ni ọkùnrin kan tún dédé yìnbọn fún Sheik Juhany, tí ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo nínú mọṣalaṣi mímọ́ náà.
Lásìkò tí Aafa Juhany ń pe ìrun Azahar ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ tí ọkùnrin náà sì já gbohùngbohùn gbà lọ́wọ́ Aafa ńlá náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí àwọn aláṣẹ mọṣalaṣi yìí mẹ́nubà ni ti ọkùnrin kan tó fẹ́ gún Aafa Sheik Sudais nígbà tí ó ń pe ìrun ní mọṣalaṣi Ka’bah ni Mecca.

Àwọn aláṣẹ mọ́sálásí ńlá ńlá méjéèjì ní ìgbésẹ̀ yìí di dandan lásìkò yìí láti pèsè ààbò fáwọn ìmáàmù wọn nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti dá wọn mọ̀ lágbààyé.
Wọ́n ní ẹ̀rọ ayélujára ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn dá àwọn aafa wọ̀nyí mọ̀ èyí ló bí káwọn ọmọ ogun ilẹ̀ máa ṣọ́ wọn kódà, tí wọ́n bá ń pèrun lọ́wọ́ nínú mọ́sálásí .
Àwọn aláṣẹ Ka’bah ní ọ̀pọ̀ èrò ló ń wá sí Mecca àti Medinah fún ìdí kan sí òmí-ìn, èyí tó fi di dandan láti dáàbò bò awọn aafa Ọlọ́run yìí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn èrò.

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ èrò ló
máa ń fẹ́ fọwọ́ kan àwọn ẹni mímọ́ yìí tàbí kí wọ́n fẹ́ mú nǹkan lára wọn láti fihàn pé àwọn pàdé e wọn ni mọ́sálásí ńlá.
Àwọn aláṣẹ mọ́sálásí méjéèjì ṣàlàyé pé, lẹ́yìn tí àwọn Aafa ńlá yìí bá parí ìrun, tí ààbò wọn ti dájú ni àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ tó ń ṣọ́ wọn náà á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kírun tiwọn, lẹ́yìn t’áwọn èrò bá ti parí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …