Home ÀKỌ̀TUN Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 18, 2019

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sí ìlú tí kò ní àdámọ́ ọ ti ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí nílùú Igbóọrà .Igbóọrà jẹ́ ìlú kan tó kalẹ̀ si agbègbè Ìbàràpá nipinlẹ Ọyọ, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé kò sí ile kan nínú ìlú náà tí wọn kò ti bí ìbejì ìbẹta tàbí ìbẹrin níbẹ̀.
Kódà, àwọn ọmọ bíbí ìlú àti àwọn a àjèjì tó bá ń gbé nínú ìlú, tó ń jẹ oúnjẹ wọn, tó sì ń mu omi wọn, ni okun ìbejì àbi ìbẹta wà nínú rẹ̀.
Ọdọọdún sì ni wọ́n máa ń ṣe ọdún ìbejì nílùú náà, èyí tó tun kò lọdun yii.
Ọ̀kan lara àwọn ọba alaye ìlú Igbóọrà, Ọba Adedamọla
Badmus, tíí ṣe Olu-Aso ti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó sọ fáwọn oníròyìn pé, ìgbàgbọ́ wà pé ọbẹ̀ ìlasa àti àmàlà dúdú ló ń sokùnfà ìbí púpọ̀ nílùú ọhun.
Gẹ́gẹ́ bí ọba Badmus ti wí, o ti to aadọta ọdun sẹyin ti ilu Igbóọrà ti gbajúmọ̀ nípa bíbí ìbejì àbi ìbẹta, ohun tó sì tun jẹ́ pàtàkì ni pé, wọn kìí fi ìbejì tọrọ owó nílùú Igbóọrà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé gbogbo ìdílé t’áwon ọmọ náà bá yà ni wọn má a ń kóríire ràn .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…