Home ÀKỌ̀TUN Àkànṣe owó oṣù lá wa olùkọ́ ń fẹ́ yàtọ̀ sí tàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì – NUT
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 6, 2019

Àkànṣe owó oṣù lá wa olùkọ́ ń fẹ́ yàtọ̀ sí tàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì – NUT

Ìjọba àpapọ̀ ; ètò ń lọ láti pèsè owó àjẹmọ́nú fáwọn olùkọ́ nígbèríko.

Àkànṣe owó oṣù lá wa olùkọ́ ń fẹ́ yàtọ̀ sí tàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì – NUT

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní béégbọn ò bá tí ì tán lábẹ́ ajá, ajá kìí yé igbe é pa, bẹ́ẹ gẹlẹ ni ọrọ rí,bí àwọn òṣìṣẹ́ tí í ṣe olùkọ́ ṣe ń ṣàyájọ́ wọn lọ́ jọ́ Karun osu Kẹwa a ọdọọdun(5/10)ni orilẹede Naijiria àti lọpọ ọ orílẹ̀èdè lagbaaye, eyi to ko lọjọ Abamẹta.
Ṣùgbọ́n ọjọ náà kò lọ lásán láì jẹ pé àwọn olùkọ́ bèèrè ọ̀kan o jọ̀kan ohun tí wọ́n ń pòùngbẹ lọwọ Ìjọba, pàtàkì ìbéèrè wọn sì ni àgbékalẹ àkànṣe owó osu fún àwọn òṣìṣẹ́.
Nígbà tó ń gbẹnu àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀, ààrẹ àpapọ̀ fun ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ jakejado orílẹ̀èdè Naijiria lásìkò ayajọ ọjọ olukọ naa, Mohammed Nasir Idris sàlàyé pé yóò dara ki àkànṣe owó osu wà fáwọn olùkọ́ k’íjọba lee safihan bí àwọn olùkọ́ ti ṣe pàtàkì si táa bá wo ọrọ ajé tí kò fara rọ yìí.
“Ìgbàgbọ́ wa ni pé àkànṣe owó osu fáwọn olùkọ́ (TSS) yóò mú ki iṣẹ́ olùkọ́ dá yàtọ̀, tí yóò si tún fún isẹ olùkọ́ ni idamọ to dara, táá si to si ipó ẹyẹ láwùjọ, a wa ń rọ Ìjọba láti tete buwọ́lu ìbéèrè yìí.”
Idris, lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lori akori ayajọ ọjọ olùkọ́ naa, ti wọ́n pe ni ‘Ọdọ Olùkọ́ ni ọjọ́ ọla fun isẹ olùkọ́’, tun kesi Ìjọba àpapọ̀ láti tètè san owó ida mẹtadinlọgbọn àti ààbọ̀ owó ajẹmọnu isẹ fáwọn olukọ to wà láwọn ileekọ girama t’ìjọba àpapọ̀, nitori eyi ni yóò jẹ ki ori àwọn olukọ naa wu láti ṣiṣẹ́ bo ṣe yẹ.
Wà yí ò, agbẹjọro agba fún Naijiria Abubakar Malami, to soju fun Ààrẹ Buhari níbi ètò tí wọn fi ń sami ayajọ olukọ náà, kede pé Ìjọba àpapọ̀ yóò fọwọ sowọpọ pẹ̀lú Ìjọba ipinlẹ lati pese eto koriya fáwọn olukọ, paapa àwọn to wà lagbegbe ìgbèríko ko.

Malami ni yàtọ̀ sí pé eyi yóò mú káwọn ọdọ setan lati ṣiṣẹ́ olùkọ́, bakan náà tun ni Ìjọba yóò seto idanilẹkọ ọ́ àtìgbàdégbà fún wọ́n, lọ́nà àti le dáńgájiá lẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́ tí wọ́n yàn láàyò .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…