Home ÀKỌ̀TUN Ilééṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria ń pa bílíọ̀nù N5.8 wọlé lójúmọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 4, 2019

Ilééṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria ń pa bílíọ̀nù N5.8 wọlé lójúmọ́

Ilééṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria ń pa bílíọ̀nù N5.8 wọlé lójúmọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe n ta o ba fẹ ba fẹ o bajẹ, o ní ba a ṣe e ṣe e.N lo bi ọrọ kan ti ọ̀ga agba asọbode ilẹ yìí sọ pé,
“Naijiria ti n jere pupọ lati igba ti a ti ti ẹnu ibode wa pa”
Ọ̀ga agba pata fun ileeṣẹ Aṣọbode Naijiria, Hameed Ali ti kede pe ileeṣẹ naa n pa biliọnu mẹrin le si biliọnu mẹfa naira “`to din
lẹgbẹrun lọna igba wọle lojoojumọ.“`
O ni kete ti ijọba Naijiria ti ẹnu bode rẹ pa ni awọn ti n pa owo yii wọle sapo ijọba apapọ bayii.
Lọjọ ru ni Ali sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lọdọ awọn ọmọ igbimọ to n mojuto eto iṣunna lọdun 2020-2022.
Loṣu kẹjọ ọdun yii ni ijoba Naijiria ti ẹnu ibode rẹ pa pẹlu awọn orilẹ-ede to mule tii bii Benin Republic.
Ijọba Naijiria ni awọn gbe igbesẹ yii lati mu ẹdinku ba awọn to n ṣe fayawọ ọja wọle.
Hameed Ali ṣalaye pe owo naa n wọle nitori pe ẹnikẹni to ba fẹ ko ọja wọ Naijiria ko ni abuja lọna ọpẹ ju ko san owo ẹnu ibode lọ.

Ali ni ẹru kọkọ ba oun nigba ti a tilẹkun ẹnubode wa pe boya owo ti a n pa wọle a dinku ṣugbọn idakeji lo pada ja si fun ijọba Naijiria.

Hameed ni koda lọjọ kan ṣoṣo loṣu to kọja, owo ti àwọn pa wọle le ni biliọnu mẹsan an naira.
O ní ohun ti àwọn tun ri ni pe awọn ọja ti wọn n ko wọle naa jẹ lati orilẹ-ede Benin .
Ali ni kete ti àwọn ti ẹnubode pa, wọn ko ni ọna miiran ju ki wọn gbe ọja wọn gba Apapa tabi TinCan Island ki àwọn si gba owo to yẹ lori ọja naa.
Nítẹsiwaju ọrọ rẹ o ní àwọn tun ti rii pe, odiwọn iye epo béntiroo ti àwọn eniyan Naijiria n lo lojumọ naa ti dinku.

Ọ̀ga agba aṣọbode fidiẹ mulẹ pe o to iwọn miliọnu mẹwaa o le jala epo meji to ti dinku nínú odiwọn epo bẹntiroo ti àwọn eniyan Naijiria n lo.
O ni eyi fihan pe epo rọbi yii ni wọn n ji gbe lọ si Benin lọna aitọ.

Ali mẹnuba ọpọ awọn ile epo to wa loju ọna ẹnubode bii Ilaro, Idi iroko ati awọn ilu si ileto ẹnu bode Naijiria.
Ni eyi ti a ti ri ẹri pe wọn ji epo rọbi ko lọ sita.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…