Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ará Eko nílò àfaradà – Babajide Sanwo olu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 3, 2019

Àwọn ará Eko nílò àfaradà – Babajide Sanwo olu

Gomina ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo olu lo n salaye yii fun awon olugbe ilu Eko. Gomina ni gbogbo aroye awon ara ilu pata ni o n de odo oun. O ni bi o n ti n ri ti inu iwe ni o n ri ti gbogbo ori ero ayelujara.
O ni koda, o n gbo gbogbo eebu sugbon obe kii mi nikun agba. Gomina ni ki awon ara ipinle Eko ni suuru nitori pe ijoba oun ko feran lati maa fowo jona.
O ni ti awon ba ni ki awon rawo le sise ona ni asiko ojo yii, o maa dabi igba ti eniyan moomo dana sun owo ni.
Gomina ni ko dara rara, nitori pe gbogbo ohun ti awon agbasese ba se ni aaro ni ojo maa wo lo ni ale. Nipa idi eyi, gomina ni ki awon eniyan jowo ni suuru die sii ki awon jo le gbadun ijoba awa ara wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…