Home ÀKỌ̀TUN Ìran Yorùbá kìí ṣe Abọ̀rìṣà…… Ọọ̀ni lfẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 28, 2019

Ìran Yorùbá kìí ṣe Abọ̀rìṣà…… Ọọ̀ni lfẹ̀

Ìran Yorùbá kìí ṣe Abọ̀rìṣà…… Ọọ̀ni lfẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe ọmọde lo lorin,iran awọn agbaagba lo nitan.Ọọni ti yanana ẹ pe ,lẹyin ede Pọtugiisi, ede Yoruba ló kù ti wọn n sọ ju ni Brazil.
Ọọni Ifẹ Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11 ti Ile Ifẹ nibi ojumọ ti n mọ wa salaye pe, iran Yoruba lo ni aṣa ati ede to dun.
O sọrọ yii nibi ayẹyẹ ayajọ ominira orilẹ-ede Brazil nilu Eko ni guusu Naijiria.

Nibi ayẹyẹ ominira Brazil yii ni Ile Ifẹ ti ṣafihan awọn ohun iṣẹmbaye iran Yoruba fun ogo ilẹ̀ Yoruba.

Helge Bandeira to jẹ aṣoju orilẹ-ede Brazil ni Naijiria naa ṣalaye pataki iran Yoruba ni Brazil ati ifẹ fun aṣa ati ede Yoruba ti awọn ara Brazil ni pupọ.

Grassiano Ọladipupọ Martins to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ọmọ Yoruba ti wọn bi si Brazil sọrọ lori ikonilẹru to sọ ọpọ ọmọ Yoruba di ero Brazil titi di oni.
Ọba Ogunwusi mẹnuba igbesẹ ti ori ade fẹ gbe bayii nipa kiko awọn wura, idẹ, baba ati awọn ohun iṣẹmbaye iran Yoruba kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye fun afihan aṣa ati awọn iṣe iran Yoruba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …