Home ÀKỌ̀TUN Sòwòrẹ̀ ń gbìmọ̀dìtẹ̀ láti gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari – Ìjọba àpapọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 24, 2019

Sòwòrẹ̀ ń gbìmọ̀dìtẹ̀ láti gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari – Ìjọba àpapọ̀

Sòwòrẹ̀ ń gbìmọ̀dìtẹ̀ láti gba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Buhari – Ìjọba àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe yooba bọ wọn ni pipẹ ọrọ n lẹ, ni in mu ki ọrọ gbọn.Bẹ ẹ,bi ọmọde o ba debi ẹru a maa ṣakọ.Bìrí bìrí, ọrọ “Revolution Now” ti fẹ ba ibo mii yọ fun Ọmọyẹle Soworẹ bayii gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe di ẹsun meje ru u latari.
Bi ọjọ ṣe ń ka ọjọ latimọle fun oludasilẹ ẹgbẹ ajafẹtọ “Revolution Now”,Ọmọyẹle Sowore, ijọba apapọ Naijiria ti fi ẹsun meje kan an.
Ẹsun pe Soworẹ ń déte láti dìtẹ̀ gba ìjọba Nàíjíríà, ẹsun lilo owo baṣubaṣu atawọn ẹsun mii ni wọn fi kan an.

Lorukọ adajọ agba orilẹ yii ati Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami to jẹ Amofin agba, ni agbẹjọro o wa ni ẹka ipẹjọ ile iṣẹ naa, Aminu Aliyu buwọlu iwe ẹsun ọhun.
Gẹlẹ to ku ọjọ kan pere ki iye ọjọ ti ijọba ni ko fi wa latimọle o pe ni wọn na iwe ẹsun meje si i eyi to si fun ile isẹ ọtẹlẹ muyẹ laṣẹ lati sọ iye ọjọ atimọle rẹ di marunlelogoji.
Tẹlẹ, ọjọ ikọkanlelogun, oṣu kẹsan an lo yẹ ki atimọle rẹwa sopin.
Ninu iwe naa, olupẹjọ fi ẹsun kan Sowore ati ajumọja rẹ, Olawale Bakare pe wọn gbimọ pọ lati gba ijọba, eyi to lodi si abala ofin 516 ninu ofin Naijiria nipa didari ifẹhonuhan lọjọ karun oṣu kẹsan pẹlu erongba lati yọ aarẹ orilẹede Naijiria loye.

Bakan naa, wọn tun fi ẹsun kan pe wọn fẹ ko ero jọ ninu oṣu kẹjọ kaakiri ipinlẹ Eko, Abuja atawọn ibomiran lorilẹ-ede Naijiria lati ṣe iwọde ifẹhonu han “Revolution Now ” lati le yọ aarẹ nipo.
Ẹwẹ, wọn tun fi ẹsun jijale lori ẹrọ ayelujara kan an eyi ti wọn ni o lodi si abala ofin 24 (1) (b) ninu ofin Naijiria.
Ẹsun lilo owo baṣubaṣu naa kun ohun ti wọn fi kan Sowore pe o lodi si abala 15 (1) ninu ofin Naijiria nipa pe wọn ni o fi owo ranṣẹ lọpọlọpọ igba nipasẹ ikani ti wọn n pe ni “swift transfer” lori ẹrọ ayelujara.

Ọjọ keji, oṣu kẹjọ ni
ọwọ sinkun ajọ DSS tẹ Sowore nile rẹ l’Eko ṣaaju ki eto iwọde ifẹhonuhan to n pete to waye ti wọn si ti gbe e si atimọle.

Ni bayii,Ọjọgbọn Wole Soyinka ti bu ẹnu àtẹ́ lu ijọba Naijiria lori ẹsun ti wọn fi kan Soworẹ.
Gbajugbaja onkọwe naa ni ẹsun ti wọn fi kan Sowore pe o fẹ ditẹ gbajọba yii ku diẹ kaato.
O fi atẹjade naa sita pe ko daa bi ijọba ti ṣe fi Sowore Omoyele si ahamọ DSS ati pe ẹsun meje ti ijọba fi kan Soworẹ yii ko tọna

Wole Soyinka ni oun ko kọkọ gba ẹsun ti oun gbọ lori Soworẹ gbọ nibẹrẹ ṣugbọn nigba ti ọrọ naa di ootọ ni o di kọọ.
Soyinka tun wa ki Ṣowore pe o kaabọ si agbo awọn ti wọn ti fẹsun kan ri.
Ko sai rọ ijọba Buhari pe ko rọra ṣe pẹlu ootọ inu nitori gbogbo ohun ti a ba ṣe loni i ,itan la n kọ fawọn iran to n bọ wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…