Home ÀKỌ̀TUN Ẹ gbóṣèlú ẹ̀taanú tì,ká jọ tún ìpínlẹ̀ Ọyọ ṣe……Makinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 19, 2019

Ẹ gbóṣèlú ẹ̀taanú tì,ká jọ tún ìpínlẹ̀ Ọyọ ṣe……Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe n ti ko ni ibẹrẹ, ni ki i lopin. Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti sajuwe aṣeyọri ẹgbẹ PDP nile igbẹjọ to n risi ọrọ idibo gẹgẹ bi i aṣeyọri otitọ to leke irọ.

Gomina naa lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ fun aduroti wọn, nigba idibo ati lẹyin idibo naa, to si parọwa si ẹgbẹ alatako, APC lati fọwọsowọpọ pẹlu oun lọna lati jumọ gbe ipinlẹ Ọyọ de ebute ogo.
Makinde lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti alukoro rẹ, ọgbẹni Taiwo Adisa buwọlu, o ni “imọran mi fun ẹgbẹ APC ni pe, ki wọn gbe oṣelu ti sẹgbẹ kan, a le pada bẹrẹ eto oṣelu lọdun 2022. Nibayi na, ẹ jẹ ka sowọpọ fun itẹsiwaju ipinlẹ Ọyọ.”

Gomina Makinde tun tẹ siwaju pe “A fẹ dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ fun aduroti wọn ki a to dibo, nigba idibo ati lẹyin idibo. Mo mọriri atilẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ fun igbagbọ wọn ninu wa, a maa tẹsiwaju lati sin yin tọkantọkan.”

Bẹẹ ni gomina naa tun fi ẹmi imore han loju opo Twitter rẹ pe otitọ ni yoo ma leke lọjọkọjọ.

Nibayii, ẹgbẹ PDP ti ki gomina onimọ ẹrọ Seyi Makinde ku oriire, fun bi igbimọ olugbẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo gomina nipinlẹ Ọyọ ṣe fi ountẹ lu pe oun ni ẹni to jawe olu bori ninu idibo ipinlẹ naa.
Ẹgbẹ naa yin Makinde fun akitiyan rẹ lati tun ipinlẹ Ọyọ ṣe, ti wọn si tun rọ lati ma bojuwẹyin ninu afojusun rẹ lati mu aye dẹrun fun awọn olugbe ipinlẹ Oyọ.
Wọn o sai gbadura fun itọni to gajulọ latoke wa fun gomina lati tukọ ipinlẹ Oyọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …