Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ wa ti tẹ Gbọ́láhàn tó pa Tóyìn l’Ákóbọ, iléeṣẹ ̀Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ fọ̀rọ̀ léde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 15, 2019

Ọwọ́ wa ti tẹ Gbọ́láhàn tó pa Tóyìn l’Ákóbọ, iléeṣẹ ̀Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ fọ̀rọ̀ léde

Ọwọ́ wa ti tẹ Gbọ́láhàn tó pa Tóyìn l’Ákóbọ, iléeṣẹ ̀Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ fọ̀rọ̀ léde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn agba bọ,wọn ni aṣepamọ lo wa, ko si aṣegbe ati pe eniyoowu to n ẹ yọlẹ ẹ da,aburu a maa yọru u wọn ṣe, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri bi ọdọkunrin ogun ọdun kan ṣe ko si saago ọlọpaa lori ẹsun ti wọn fi kan an pe, o pa arabinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan nilu Ibadan.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Shina Olukolu ni ọmọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Gbọlahan Ismaila, la ijoko mọ arabinrin ọun, ti orukọ rẹ n jẹ Toyin Olubọwale lori, lẹyin to fi tipatikuuku baa lajọṣepọ.

Ọga ọlọpaa naa ṣalaye pe, ọlọkada to gbe afurasi naa lọ si ile arabinrin yii lo kẹẹfin ọgbẹ ẹjẹ ni ika ọwọ rẹ nigba ti o n gbe e pada si agbegbe Oju-irin Akobọ.
Eyi lo fu- un lara nitori awọn ohun ti ko beti mu to gbọ, lasiko to n duro de Gbọ́láhàn nita ile naa.
Nigba ti ọlọkada yii pada si ile ti Toyin n gbe, lẹyin to ja Gbọ́láhàn silẹ tan, to ri ti awọn ẹbi obinrin naa n sunkun, lo to han si nipa ohun to ṣẹlẹ.
Ọlọkada yii lo ṣalaye fun awọn ẹbi arabinrin naa pe, oun mọ oniṣẹ laabi to pa arabinrin naa, ti wọn fi lọ fi ọlọpaa gbe e.

Bakan naa ni Olukolu tẹsiwaju pe, ọwọ tun tẹ awọn afurasi meji pẹlu Gbọlahan. Akọkọ ni Oyedeji Blessing ti wọn fẹsun kan pe o gba ẹrọ ibanisọrọ Toyin ti Gbọlahan ji, lẹyin to pa a tan.
O ni wọn tun mu Oyekọla Mumuni, ti o n tun foonu ṣe ni tirẹ, oun ni wọn lo ran wọn lọwọ lati pa awọn ohun to wa lori ẹrọ ibanisọrọ naa rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…