Home ÀKỌ̀TUN Oun tí ó yẹ ká gbájú mọ́ lásìko yìí ni ìsọ̀kan àwa Yorùbá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 14, 2019

Oun tí ó yẹ ká gbájú mọ́ lásìko yìí ni ìsọ̀kan àwa Yorùbá

Oun tí ó yẹ ká gbájú mọ́ lásìko yìí ni ìsọ̀kan àwa Yorùbá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Koko pataki to jẹ yọ re e, lati inu ọrọ akọkọ ti Ọjọgbọn Banji Akintoye fi sita lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu u Eko.
Gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ilẹ̀ káàrọ́ọ̀-òò-jíire jakejado agbaye (Assembly of All Yoruba Groups, Worldwide) lo ṣaaju dibo yan Akintoye gẹgẹ bii asaaju ọmọ ilẹ Yoruba loṣu kẹjọ ọdun yii.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ Akintoye ni oun gba oye naa tọwọ tẹsẹ ti o si pe fun ifọwọsowọpọ awọn ọmọ Yoruba.

Ọjọgbọn Banji ni o ṣe pataki lati wo awọn ipenija to n doju kọ ilẹ Yoruba paapa julọ eleyi to ni ṣe pẹlu aabo.
O ni inu ibẹrubojo lawọn eeyan wa amọ, awọn ọmọ Yoruba ko ṣe ”ojo lati doju kọ awọn to fẹ gba ilẹ mọ wọn lọwọ”
Bakan naa lo sọ pe iran Yoruba yoo jẹwọ orukọ wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe ṣe saaju lọdun 1840 nigba ti awọn kan fẹ kogun ja wọn.
Laipẹ́ yi ni awọn igun ẹgbẹ asaaju Yoruba kan n sọ pe Ọjọgbọn Akintoye ti kọ ipo ti wọn yan an si.
Oun ati Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni wọn jọ du ipo yi ki o to ja mọ ọ lọwọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…