Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹ́jọ́ tó ń gb’ẹ́sùn ìdìbò wọ́gilé ẹjọ́ tí Ajimọbi pè tako Kọla Balogun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 12, 2019

Ilé ẹ́jọ́ tó ń gb’ẹ́sùn ìdìbò wọ́gilé ẹjọ́ tí Ajimọbi pè tako Kọla Balogun

Ilé ẹ́jọ́ tó ń gb’ẹ́sùn ìdìbò wọ́gilé ẹjọ́ tí Ajimọbi pè tako Kọla Balogun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe kangun kangun kangun gbọdọ kangun si bikan.N ti ko si nibẹrẹ ni kii lopin.Ni bayii, idajọ ti waye latari ẹjọ ti Gomina tẹlẹri,Abiola Ajimobi pe tako Omowe Muhammed Kọla Balogun,bẹ Sinetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Oyọ, Kola Balogun ti sọrọ lori ifidirẹmi Sinetọ Abiola Ajimobi to pẹjọ tako lori ipo Sinetọ.
Balogun ni idajọ naa jẹ aṣeyọri fun iṣejọba awa-ara-wa ni nilẹ yii ati fawọn eeyan ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Oyo.
O wa sọ pe ti Sinetọ Ajimobi ba fẹ maa ba Ọlọrun ja lori idajọ naa ”ki o mura sii, a o wo ibi ti yoo fosupa alẹ rina de”

Sinetọ naa sọ ọrọ yi nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin aṣeyọri rẹ nilu Ibadan.
Saaju ni Ile ẹjọ to n gb’ẹsun idibo ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan ti wọgile ẹjọ ti gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ọyọ Ṣinetọ Isiaka Abiọla Ajimọbi pe.
O pe ẹjọ yii tako ẹni ti Ajọ lNEC kede gẹgẹ bi olubori ninu idije si ipọ Sinetọ ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Kọla Balogun.Adajọ Anthony Apkovi ti o ṣoju igbimọ ẹlẹni mẹta ti o risi igbẹjọ naa lo kede abajade iṣẹ iwadi i wọn lọjọ Iṣẹgun.Lara awọn ẹsun ti Abiọla Ajimọbi fi kan Kọla Balogun ni aiṣe eto idibo abẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ki o to dije, ṣiṣe amulo awọn janduku lati ji apoti ibo gbe, titọwọ bọ akọsilẹ ẹsi ibo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn ile ẹjọ ni gbogbo ẹsun naa ni ko ri ẹsẹ walẹ nitori aisi ẹri aridaju.Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn akọrọyin, ọkan lara awọn agbẹjọro fun Sẹnetọ Kọla Balogun, Amofin Isiaka Abiọla Ọlagunju ṣe alaye pe ohun ti ko kan Ajimọbi lo n dasi.
O ni ki lo kan Ajimọbi nipasẹ ẹsun ti o fi kan pe Sẹnetọ Balogun ko kopa ninu eto idibo abẹnu ki o to dije ninu ẹgbẹ oṣẹ lu PDP. O ni bi sokoto ko balẹ,kin ni atojubọ
talagbafọ ,s’oun ni yoo wọ ?O fẹ sinsin ku,o n fọwọ ra imu.
O ni kin lo kan Ajimọbi nipasẹ ẹsun ti o fi kan pe Sẹnetọ Balogun ko kopa ninu eto idibo abẹnu ki o to dije ninu ẹgbẹ oṣẹlu PDP.

Ọlagunju tẹsiwaju wi pe ifẹ ọkan awọn ara ilu lo gbe onibara oun de ipo ti ko si ni ohunkohun ṣe pẹlu ẹsun mago-mago ti ẹgbẹ oṣelu APC fi kan an.O ni ohun idunnu nla lo jẹ wi pe idajọ naa so eso rere fun Sẹnetọ Kọla Balọgun lẹyin ọpọlọpọ atotonu.

A gbiyanju lati ba awọn agbẹjọrọ ati alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ lẹyin idajọ naa, ṣugbọn pabo lo jasi.Ariwo ọkan-o-jọkan orin lo gba ẹnu gbogbo awọn alatilẹyin Sẹnetọ Kọla Balogun kan lẹyin idajọ naa.
Kọla Balogun ti o ti fi igba kan ri jẹ kọmiṣọna fun karakata ati amojuto awọn ẹgbẹ alajẹṣẹku ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn kede gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olubori ninu eto idibo si ipo Ṣẹnetọ ẹkun idibo guusu ipinlẹ Ọyọ naa.

Eto idibo naa lo waye lọjọ kẹtaleogun, oṣu keji ọdun 2019.
Sinatọ Kọla Balogun ni akojọpọ ibo 105,720, ti gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ Abiọla Ajimobi si ṣe ipo keji pẹlu onka ibo 92,218.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…